Kà nípa bí o ṣe lè dènà àìsàn ọkàn, ìgbàgbé láti ẹni ọgbọ̀n ọdún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko sẹni to le fi ọwọ ọjọ ogbo sọya pe yoo kan oun, idi naa si ni pe Adaniwaye lo n pin ẹmi gigun.
Ṣugbọn bi ori ba ba eeyan ṣe e to dagba wọ ọgbọn ọdun, to si tun ni anfaani lati tẹsiwaju ju bẹẹ lọ, awọn ohun kan wa ti awọn onimọ nipa ilera, gba a niyanju lati maa ṣe fun alaafia ṣaaju ọjọ ogbo.
Alaye wọn ni pe lati ọgbọn ọdun yii ni bi ara yoo ṣe ri nigba ti eeyan ba pe aadọrin ọdun (70) yoo ti bẹrẹ.
Bi awọn onimọ ijinlẹ ti wi, nigba ti eeyan ba wọ ọgbọn ọdun ni awọn ẹya ara bii egungun ati iṣan yoo bẹrẹ si fi awọn apẹẹrẹ agba han.
Nigba ti eeyan yoo ba fi pe ọgọrin ọdun (80 years), yoo ri i pe agbara ti dinku, eeyan si le maa gbagbe awon nnkan yatọ si igba to ṣi wa ni ọjọ ori to kere.
Igba naa ni ilana oorun yoo dinku, eeyan le maa sun nirọlẹ, ko di alẹ ki oorun ma wa, tabi ki eeyan maa tete ji ju bo ṣe yẹ lọ.
Koda, wọn ni o ṣee ṣe ki agbalagba naa koju aisan kan to lagbara.
Eric Verdan, Adari Buck Institute for Aging Research, ni California, sọ pe: "Ọpọ eeyan le ni ireti lati gbele aye fun aadọrun si ọdun marundinlọgọrun-un (90- 95) pẹlu alaafia ara, iyẹn bi wọn ba tun ilana igbe-aye wọn ṣe."
Bawo ni eeyan yoo ṣe tun ilana igbesi aye rẹ ṣe?
Gẹgẹ bi alaye Eric Verdan, ko si gbedeke fun iye ọjọ ori ti eeyan ti le yi bo ṣe n ba a bọ tẹlẹ pada.
Lara awọn ilana to la kalẹ ti eeyan le fi yi ilana igbe-aye rẹ pada ni:
- Siṣe ere idaraya
- Ṣiṣe atunṣe si iru ounjẹ ti o ti n jẹ bọ latẹyin
- Din ọti mimu ku bi o ba jẹ ẹni to n mu oti, to ba si ṣee ṣe lati dẹkun rẹ pata, o daa.
Ṣugbọn ṣaa, ki eeyan tete bẹrẹ ayipada naa lo ni yoo mu esi to dara ju wa.
Bakan naa, Paul Morgan, olukọ agba nipa ounjẹ ati ere idaraya ni Manchester Metropolitan University, fidi ẹ mulẹ, pe bi awọn to n sa ere ije ati awọn elere idaraya miran ṣe maa n dagba, yatọ si ti awọn eeyan yoku.
"Wọn ni ọkan to pe ju awa yoku lọ, bẹẹ ni iṣan wọn n ṣiṣẹ daadaa ju tiwa lọ, nigba ti wọn ba n dagba nikan ni yoo maa dinku.
"Gbogbo eeyan lo le kẹkọọ lara eyi, ki wọn mura si ayipada rere ti yoo fun ọjọ ogbo wọn ni alaafia."
Bẹẹ ni Morgan wi.
Awọn ti ọjọ ori wọn ti kọja aadọrin maa n saba koju iṣoro ṣiṣubu
Paul Morgan tẹsiwaju pe o saba maa n waye pe kawọn ti ọjọ ori wọn ti kọja aadọrin (70) soke maa ṣubu, irin wọn ko si ni i yá mọ.
O ni eyi lo ṣe yẹ ki eeyan karamaasiki awọn ere idaraya ti wọn fi ẹsẹ̀ ṣe, ṣaaju ọjọ ogbo.
- Ran iranti ati ọpọlọ rẹ lọwọ
Gẹgẹ bi a ṣe n ran ilera iṣan ati ọkan pẹlu awọn ẹya ara miran lọwọ, bẹẹ naa lo ṣe pataki lati ṣe fun ọpọlọ wa. Nigba ti a ba si ti pe ọgbọn ọdun, a le bẹrẹ eyi.
Awọn ọna ti yoo mu eyi wa si imuṣẹ bi awọn onimọ ijinlẹ ṣe wi ni:
Riri daju pe ẹnu rẹ n wa ni imọtoto, maa ṣabẹwo si awọn dokita eleyin deede.
- Maa fọ eyin ẹnu rẹ deede pẹlu.
- Yago fun siga mimu, ki o si din ṣuga ti o n jẹ ku.
Gbogbo eyi n kopa pupọ ninu ki eeyan maa ranti nnkan deede, ki ọpọlọ rẹ si maa ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
Jijẹ eso ati awọn ounje ti ko dun ju naa dara fun ọ lati fun ọ ni ọjọ ogbo rere.
Ọti mimu maa n jẹ ki eeyan tete dagba ju ọjọ ori rẹ lọ, bi o ba ti pe ọgbọn ọdun, din ọti mimu rẹ ku tabi ki o ṣiwọ rẹ patapata
Ni itẹsiwaju alaye, Verdan sọ pe ọti mimu maa n ṣe akoba fun bi o ṣe yẹ ki eeyan sun, eyi yoo si koba ọpọlọ.
Bi eeyan ko ba sun to, yoo nipa lori ọpọlọ, o si le maa gbagbe nnkan.
O ni o yẹ ki eeyan ri i daju pe asiko oorun rẹ lalẹ ko yipada, asiko to n ji laaarọ naa ko si pada, nitori agọ ara maa n to ara rẹ nigba ti eeyan ba sun daadaa.
Ti oorun ko ba waa ṣee ṣe fun ọ bayii nitori idi kan tabi omiran, ounjẹ ti yoo to ara rẹ sipo ire ni wọn ni ko o fi rọpo ibẹ ṣe lati ọgbọn ọdun lọ.
- Máa gba ààwẹ̀
Verdan fi kun un pe oore nla ti a le ṣe fun ara wa loju ọjọ ni aawẹ gbigba, nitori ara maa n sinmi lasiko aawẹ.
"Nigba ti o ba gba aawe, ara rẹ yoo kuro ni abala dída ounjẹ, yoo yipada si atunṣe ara naa funra rẹ.
"Nitori ẹ ni mo ṣe maa n sọ fun awọn eeyan pe nigba ti o ba jẹun, o n kọ ara rẹ bii eni kọle ni, nigba ti o ba gba aawẹ, o n tun ara rẹ ṣe ni."
Jijẹ eso ati ewebe tun dara fun ayipada rere nisinyi ati lọjọ ogbo, yatọ si jijẹ awọn ijẹkujẹ inu agolo ti wọn ti po orisiriṣi nnkan mọ.
Titẹ le ilana igbesi-aye alaafia nigba ti o wa ni ọgbọn ọdun, yoo dena aisan ọkan, airanti nnkan, aile rin ati bẹẹ bẹẹ lọ fun ọ lọjọ iwaju.












