Orílẹ̀èdè Canada dá ọmọ Naijiria 366 padà sílé

Aworan awọn eeyan ti wọn tò lọ́wọọ̀wọ́ pẹlu ọra lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko din ni ọtale-lọọdunrun-o-le mefa (366)ọmọ orilẹede Naijiria ti orilẹede Canada, sọ loko pada si Naijiria laaarin oṣu Kin-in-ni si Ikẹwaa ọdun 2025 to ṣẹṣẹ pari yii.

Gẹgẹ bi akọsilẹ lati ẹka to n ri si eyi ni Canada, Canada Border Services Agency, (CBSA) ṣe wi, o tun ṣi ku eeyan 974 ti Canada fẹ da pada si Naijiria ti wọn ti wa.

Akọsilẹ naa fi han pe Naijiria lo wa nipo kẹsan-an ninu awọn mẹwaa akọkọ ti Canada de eeyan wọn pada silẹ.

Idapada silẹ ti Canada n ṣe yii, wa ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe mura si iwọle-jade awọn arinrinajo, paapaa awọn to n wọle siluu naa lọna aitọ.

O kere tan, ẹka to n ri si eyi n le irinwo eeyan jade lọsẹ bi akọsilẹ ṣe sọ.

Ni 2024 si 2025, eeyan 18,048 ni wọn le kuro niluu naa, owo ti wọn si na lori eyi jẹ $78m.

Ni 2019, wọn le ọmọ Naijiria 339 wale,302 ni 2020, 242 in 2021 ati 199 ni 2022 ati 366 bayii.

Awọn orilẹede mẹwaa ti wọn wa loke tente ninu idapada naa ni: Mexico (3,972), India (2,831), Haiti (2,012), Colombia (737), Romania (672), United States (656), Venezuela (562), China (385), Nigeria (366), ati Pakistan (359).

Ki lo de ti Canada n da awọn eeyan pada sile?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Labẹ ofin to da aabo bo awọn to n ṣe atipo lorilẹede ti ki i ṣe tiwọn, ẹka CBSA ni anfaani lati fi ofin le ajeji ti wọn ba ri I pe o yẹ ki wọn le jade.

Yatọ si eyi, awọn ẹlomi-in le ma kunju oṣuwọn lati wọle siluu naa rara, eyi si le jẹ nitori aabo, iwa ọdaran, aini ilera pipe, ai ni owo to to, fifi ẹlomiran rọpo ara ẹni, aitẹle ofin irinna ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ida mẹtalelọgọrin (83%) awọn ti wọn fẹ le jade lo jẹ wọn ko buwọ lu iwe wọn lati gbe Canada, nitori idaamu ti wọn n koju nibi ti wọn ti n bọ (asylum).

Awọn ti wọn le nitori iwa ọdaran jẹ nnkan bii ida mẹrin (4%).

Labẹ ofin ilẹ Canada, ọna mẹta ni wọn fi lè lé eeyan jade niluu naa:

Akọkọ ni ofin to de kikuro laarin ọgbọnjọ (30 days).

Ikeji ni eyi to fofin de ajeji lati ma wọ Canada laaarin ọdun kan si marun-un.

Ikẹta ni sisọ eeyan loko pada siluu rẹ (deportation order), ti ẹni naa ko ni I le wọ Canada mọ afi to ba gba aṣẹ to yatọ gedegbe.

Ninu alaye ijọba Canada, wọn ni awọn mura si dida awọn eeyan pada siluu wọn lati jẹ ki onka ajeji tawọn fẹ ma ṣe kọja iye to yẹ.

Idi miran tun ni pe ile gbigbe ti n di iṣoro latari awọn ajeji ti wọn n ya wọ ilu naa.

Iṣoro iṣẹ ṣiṣe ni wọn lo ṣikẹta, aabo ẹnu ibode ni wọn lo

ṣikẹrin.

Aarẹ ẹgbẹ awọn lọya to n ri si ọrọ awọn to n ṣe atipo ni Canada, Aisling Bondy, sọ pe o ṣee ṣe ki ọpọ eeyan ma le ni anfaani gbigbe ilu naa labẹ atipo ṣiṣe mọ.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, orilẹede Canada jẹ ọkan lara awọn ilu ti awọn ọmọ Naijiria maa n sa lọ lati wa igbesi aye irọrun.

Ikaniyan ti wọn ṣe ni Canada ni 2021, fi han pe o le ni ẹgbẹrun lọna ogoji ọmọ Naijiria ti wọn n gbe ni Canada lati 2016 si 2021.

Ni oṣu kẹrin akọkọ ninu ọdun 2024, ọmọ Naijiria 6, 600 ni akọsilẹ sọ pe wọn tun wọ Canada bii olugbe tuntun.

Laaarin 2005 si 2024, o le ni ọmọ Naijiria 71,459 ti wọn gba iwe igbeluu bii ọmọ Canada, eyi to mu Naijiria wa ni ipo kẹwaa ninu awọn to n gba iwe igbeluu Canada.

Latilẹ, awọn agbalagba ti ko fi bẹẹ si agbara iṣẹ fun mọ lo pọ ninu awọn ọmọ oniluu ni Canada, bẹẹ si ni awọn iṣẹ kan naa wa ti wọn ko ni anito oṣiṣẹ fun.

Eyi lo jẹ idi pataki ti awọn akọṣẹmọṣẹ ọmọ Naijiria ati awọn akẹkọọ fi n gba Canada lọ.