Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fòntẹ̀ lu ìdájọ́ ikú fún Abdulmalik tó ṣekúpa ọmọ ọdún márùn ún Hanifa

Oríṣun àwòrán, NG Police/Hanifa family
Ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Kano ti fontẹ lu idajọ iku fun Abdulmalik Tanko, to ji ọmọ ọdun marun un, Hanifa Abubakar gbe ti o si pa a.
Adajọ A.R. Muhammad yi ẹjọ kotẹmilọrun ti Tanko pe lori idajọ iku ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano da fun un tẹlẹ danu.
Ṣaaju ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano ti dajọ wi pe ki wọn lọ yẹgi fun Tanko lẹyin ti ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun fidi rẹ mulẹ pe ile ẹjọ giga to dajọ iku fun Tanko ṣe ohun to yẹ ki o ṣe labẹ ofin.
Adajọ Muhammad ni awijare Tanko nile ẹjọ kotemilọrun ko lẹsẹ nlẹ rara, ati pe igbimọ olupẹjọ ni ẹri to daju lori ẹjọ ti wọn pe e.
Adajọ wa sọ pe ko si idi ti ile ejọ kotẹmilọrun fi le yi ẹjọ ti ile ẹjọ giga ti da lori ọrọ naa tẹlẹ danu.
Adajọ Muhammad tun rọ awọn tọrọ kan lati ṣiṣẹ lori bi idajọ naa yoo ṣe di mimuṣẹ lọna to ba ofin mu.
Lẹyin ti Tanko beere fun ₦6m owo itusilẹ lọwọ awọn obi Hanifa lo pa a
Ninu oṣu Kejila ọdun 2021 ni Tanko, adari ile ẹkọ Noble Kids Academy to wa nijọba ibilẹ Nassarawa ni Kano ji Hanifa Abubakar to jẹ ọmọ ọdun marun un nigba naa gbe.
Ti ẹ o ba gbagbe, Hanifa jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa.
Lẹyin ti Tanko beere fun miliọnu mẹfa naira (₦6m) owo itusilẹ lọwọ awọn obi Hanifa ni o fun un ni ogun peku peku jẹ ti ọmọ naa si gbabẹ ku.
Tanko lo pa ọmọde yii bi iroyin ṣe wi, o si sinku rẹ sinu iho kan ti ko jin.
Aṣiri tu lẹyin iwadii ọlọpaa, wọn si fọwọ ofin mu Tanko; ẹni ọdun mejidinlogoji nigba naa,
Ọrọ naa bi ọpọ eeyan ninu pẹlu bi o ṣe jẹ pe Tanko gan an ni adari ile ẹkọ ti wọn fi ọmọdebinrin naa si lati maa mojuto o.
Ọjọ kẹrinlelologun oṣu Kinni ọdun 2022 ni Tanko farahan nile ẹjọ pẹlu Isyaku Hashim ati Fatima Jibril lori ẹsun igbimọpọ lati huwa ọdaran, ijinigbe ati ẹsun ipaniyan.
Lọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keje ọdun 2022 ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano dajọ iku fun Tanko ati Hashim.
Adajọ Usman Na'abba tun dajọ ẹwọn ọdun meji Fatima Jibril.















