Ṣáká lára mi dá, mo ń lo Aspirin ju iye tí dókítà ní kí n máa lò lójúmọ́ - Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump sọ̀rọ̀ lórí ìlera rẹ̀

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ń wo ẹ̀gbẹ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Max Matza
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti sọ pé òun wà ní ìlera pípé, tí òun sì máa ń lo oògùn aspirin ju bí àwọn dókítà ṣe sọ pé kí òun máa lò lọ.

Ó ní òun máa ń lo àtíkè láti fi bo àwọn àpá tó wà lọ́wọ́ òun àti pé òun kìí ṣe eré ìdárayá báwọn kan ṣe máa ń ṣe.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe nípa ìlera rẹ̀, Trump sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn The Wall Street Journal pé òun ṣe àyẹ̀wò CT scan nínú oṣù Kẹwàá lẹ́yìn tó ṣèṣì sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé òun ti ṣe àyẹ̀wò MRI scan.

Trump, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin, ni ààrẹ Amẹ́ríkà tó dàgbà jùlọ tí wọ́n dìbò yàn, tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì ti di ohun tó ń mú awuyewuye dání.

Ó jíyan rẹ̀ fún iléeṣẹ́ ìròyìn náà pé òun kò gbọ́rọ̀ dáadáa tàbí sún lọ níbi àwọn ètò tó ń wáyé lásìkò yìí ní ilé ìjọba White House.

Trump sọ pé òun máa ń lò kọjá iye oògùn aspirin táwọn dókítà sọ pé kí òun máa lò lọ láti bíi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń jẹ́ kí egbò wà lára òun.

"Wọ́n sọ pé aspirin dára láti jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tínrín lára, mi ò sì fẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ kíki máa jáde láti ọkàn mi," Trump sọ.

Ó ní òun máa ń lo aspirin 325mg lójúmọ́ lòdì sí 81mg táwọn dókítà máa ń sọ pé kí èèyàn lò lójúmọ́.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Èyí tó kéré si ni wọ́n máa ń fẹ́ kí n lò," ó sọ.

Ṣùgbọ́n ó ní òun kò fẹ́ ṣe àyípadà àwọn nǹkan tí òun ti ń ṣe láti ọdún pípẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí ilé ìwòsàn Mayo Clinic ṣe sọ, ewu láti ní àìsàn ọkàn àti rọmọ́lápá rọmọ́lẹsẹ̀ bí èèyàn bá ṣe ń dàgbà si, tí lílo aspirin sì máa ń dènà kí ẹ̀jẹ̀ díẹ̀, tó sì máa ń dènà kí ẹ̀jẹ̀ dì.

Àmọ́ ilé ìwòsàn náà tún ṣèkìlọ̀ pé èèyàn lè máa ṣẹ̀jẹ̀ púpọ̀ bí èèyàn bá ṣe ń dàgbà si. Wọ́n ní iye aspirin tí èèyàn le máa lò lójúmọ́ wà láàárín 75mg sí 325mg.

Bákan náà ni Trump tún sọ̀rọ̀ lórí àyẹ̀wò tó ṣe ní Walter Reed National Medical Center èyí tó ti kọ́kọ́ pè ní MRI scan.

"Kìí ṣe MRI, Trump sọ fún Journal. "Ó kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àyẹ̀wò scan lásán ni.

Dókítà Trump kan, Sean Barbabella sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé CT scan ni Trump ṣe láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Trump kò ní àìsàn kankan àti pé àyẹ̀wò náà kò ṣàfihàn àìlera kankan.

Nígbà tí wọ́n fi ṣàwárí àìsàn "chronic venous insufficiency", lára Trump, àìsàn tó wọ́pọ̀ lára àwọn àgbàlagbà, wọ́n ní kó máa wọ ìbọ̀sẹ̀ ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti máa wọ̀ ọ́.

"Mi ò fẹ́ràn láti máa wọ̀ wọ́n," Trump sọ, tọ sì fi kun pé òun máa ń dìde lórí ìjòkòó láti rìn èyí tó ní ó ti mú àdínkù bí ẹsẹ̀ òun ṣe máa ń wú.

Bákan náà ló ní òun kò fẹ́ràn láti máa ṣe àwọn eré ìdárayá táwọn èèyàn máa ń ṣe, tó sì jẹ́ pé gbígba gọ́ọ̀fù nìkan lòhun fẹ́ràn.

Ààrẹ náà tún sọ pé òun kò sùn lọ lásìkò ìpàdé kankan rí, tó sì jẹ́ pé òun kàn máa ń dijú lásìkò tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.

Lórí àwọn ègbò tí wọ́n máa ń rí lọ́wọ́ òun nínú àwọn àwòrán kankan, Trump ní òun máa ń gbé àtíkè kiri báyìí.

Trump ṣàlàyé pé òun kò ní ìṣòro pẹ̀lú gbígbọ́ ọ̀rọ̀, tó sì ní lásìkò tí òun bá ṣẹ́jú ni àwọn ayàwòrán máa ń ya òun, tó sì máa ń dàbí ẹni pé òun ń sùn ni.

Barbabella sọ nínú àtẹ̀jáde náà pé Trump wà ní ìlera pípé, tó sì lè ṣiṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀ èdè náà dáadáa.

Àkọlé fídíò,