Iná ṣẹ́yọ nílé ọtí lọ́jọ́ ọdún tuntun, ọ̀pọ̀ èèyàn kú, ọgọ́rùn-ún farapa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti a n kọ iroyin lọwọ, a ko ti I le sọ pato iye eeyan to ku loni ọjọ akọko ninu oṣu Kin-in-ni ọdun 2026, nigba ti ina ṣẹyọ nibi igbafẹ ati ile ọti Le Constellation, Crans-Montana lorilẹde Switzerland.
Iroyin sọ pe o le ni ogoji eeyan to ti dagbere faye latati ina ọhun, ati pe o ti le ni ọgọrun-un kan eeyan to farapa.
Gẹgẹ bi awọn o ṣoju mi koro ṣe ṣalaye fun BBC, nnkan bii aago kan aabọ ọsan ọni ni ina deede ṣẹyọ nile igbafẹ to wa ni Guusu-Iwọ-Oorun Switzerland naa.
Ibi igbafẹ yii jẹ aaye to maa n kun fun awọn onifaaji, paapaa awọn ọdọ, yala lasiko ọdun tabi ni ọjọ lasan.
Awọn to farakaaṣa lonii yii lọ fun faaji ọdun ni bi a ṣe gbọ, ọjọ ori pupọ ninu wọn si wa laaarin ọdun mẹrindinlogun (16) si mẹrindinlọgbọn (26).
Bawo ni ina ṣe waye?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko ti I sẹni to le fidi ohun to fa ina ọhun mulẹ lasiko yii, ṣugbọn awọn alaṣẹ orilẹede naa sọ pe ki I ṣe ikọlu.
Igbagbọ awọn kan ninu ile ọti naa ni pe abẹla ti awọn to n ṣe ọjọọbi tan si ori igo ọti lo fa ina to jo orule, to si di ohun to sọlẹ si awọn onifaaji lori.
Gẹgẹ bi awọn o ṣoju mi koro ṣe wi, ẹya ọlọkan-o-jọkan ni awọn eeyan ti ijamba yii kan.
Ọpọ awọn ti ina ọhun jo ni a gbọ pe o jo wọn gidi, bẹẹ ni ẹka itọju awọn to wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, ti kun patapata nileewosan, bi awọn alaṣẹ ileewosan Swiss kan ṣe sọ.
Adari Lausanne University Hospital, ṣalaye pe eeyan mejilelogun ni awọn n tọju lọwọ lọdọ awọn.
Claire Charmet, sọ fun iwe iroyin Swiss pe awọn ti ọjọ ori wọn wa laaarin 16 si 26 lo farapa ju.
Charmet ṣalaye pe yoo pẹ kawọn eeyan naa too ni alaafia, o ni o le to oṣu, nitori wọn farapa gan-an.
"A ko ti I le sọ bayii boya ewu wa lori wọn tabi bẹẹ kọ.
"Ohun to ṣe koko bayii ni lati gba wọn wọle, ka ṣe akọsilẹ orukọ wọn ka si jẹ ki awọn ẹbi wọn mọ."
"Mo ri awon eeyan to n jona lati ori de ẹsẹ, ko si aṣọ lara wọn mọ"
Ẹnikan lara awọn o ṣoju mi koro, ṣalaye pe oun wọnu ina to n jo naa lati da aabo bo awọn to wa nibẹ
" A gburo ibugbamu kan to lagbara gan-an, lẹyin iyẹn ni a ri eefin to n yọ"
"Mo ro pe aburo mi wa ninu ibẹ ni, tori e ni mo ṣe gbiyanju lati fọ ferese kawọn eeyan le jade."
"Nigba ti mo wọle, mo ri awon eeyan to n jona lati ori de ẹsẹ, ko si aṣọ lara wọn mọ, o ba eeyan lẹru gan-an "
Awọn ọmọ ilẹ Faranse meji kan, Emma ati Albane, ti wọn wa ninu ile ọti naa sọ pe ka diju ka la a ni ina ọhun fi ṣẹyọ.
Wọn ni laaarin iṣẹju perete ni orule gbina, to si ṣoro lati ko awọn eeyan jade latari ọna abajade to kere.
Awọn mejeeji sọ pe awọn gba pe abẹla ti wọn tan sunmọ orule lo fa ina .
Ṣaa, ọkọ ofurufu agberapaa (helicopter) mẹwaa, awọn ọkọ to n gbe oku ati alaaye (ambulances) ogoji ati awọn oṣiṣẹ alaabo aadọjọ (150) ni wọn ti balẹ sibi iṣẹlẹ naa.














