Ohun tí a mọ̀ rèé nípa obìnrin tó fẹ́sùn kàn pé wọ́n sọ iná sílé òun ní Ilorin nítorí pé òun ń ṣe ìṣẹ̀ṣe

Asabi Olorisa kawọ gbera pẹlu aworan ile rẹ to jona
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni owurọ ọjọ Abamẹta ni fidio kan gba ori ayelujara nibi ti obinrin kan ti n fẹsun kan pe wọn sọ ina sile oun ni agbegbe Isalekoto, Ojagboro, ilu Ilorin nitori oun jẹ oniṣẹṣe.

Obìnrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Toyin Aṣabi Olorisa ladugbo lo ke gbajare síta latari ina to jo ile rẹ tan patapata.

Iṣẹlẹ jàmbá ina naa to jo gbogbo ile oniyara mẹjọ naa kanlẹ ṣẹlẹ lọjọ ọdún tuntun ọjọ Kiini, oṣu Kiini.

Lasiko to n ba akọroyin BBC News Yorùbá sọrọ nipa iṣẹlẹ yii Asabi Olorisa sọ pe oun o si nile lasiko iṣẹlẹ naa.

O ni oun ti lọ si ilu abinibi oun lati lọ sọdun tuntun nibẹ ko to di pe wọn pe oun pe ile oun n jona lọwọ.

O ṣalaye pe nnkan bi aago mẹjọ alẹ ọjọ Kiini, osu Kiini ọdun yii ni wọn pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe ile oun n jona.

Asabi Olorisa sọ pe nigba ti oun de, gbogbo ile ti jona tan pẹlu gbogbo dukia ti oun ni ninu ile.

Wọ́n sọ iná sí ilé mi nítorí mọ̀ ń ṣe ìṣẹ̀ṣe

O wa fẹsun kan pe awọn kan ni wọn fi ina si ile oun nitori iṣẹṣe ti oun n ṣe.

Obinrin naa sọ pe ni oṣu Kọkanla ọdun to kọja lawọn kan pe ọmọ oun ti orukọ rẹ n jẹ Dare pe ko kilọ fun oun lori iṣẹse ti oun n ṣe, pé tí oun o ba jawọ, wọn yóò fi ina sí ile oun, ti oun si lọ fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.

Asabi Olorisa ni eyi lo jẹ ki oun ro o pe awọn eeyan naa ni wọn mọọmọ sọ ina si ile oun nigba ti oun ko si nile.

Ẹwẹ, Aṣabi Olorisa ti kesi awọn agbofinro ati ijọba lati wadii ohun to ṣokunfa ijamba ina ati pe ki wọn wadii rẹ to ba jẹ pe awọn kan lo wa nidii rẹ, ki iya naa ma ba a jẹ oun gbe.

O ni gbogbo dukia oun to fi mọ goolu ati aṣọ lo jona ayafi ikoko Osun nikan ti ko jona.

Àwòrán ilé Asabi Olorisa to jona ku

'Àwa ò mọ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà'

BBC News Yoruba kan si awọn awọn ara adugbo naa lati gbọ ti ẹnu wọn lori ẹsun ti obinrin naa fi kan.

Alaga ẹgbẹ awọn onile ladugbo Isalekoko, Ojagboro, Alhaji Yẹkini Ọlọruntele sọ pe ọrọ ti obinrin naa sọ kori bẹẹ rara.

Alhaji Ọlọruntẹlẹ ṣalaye pe lati bii ọdun mejidinlogun sẹyin lawọn ati obinrin naa ti jọ gbe adugbo naa lai si wahala kankan pẹlu bi o ṣe n ṣe iṣẹṣe rẹ.

O sọ pe loootọ ni pe obinrin naa ko si nile lasiko ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ, sugbọn ẹnikan sọ pe wọn ri ọkan lara awọn ọmọ rẹ to wọle.

Alhaji Ọlọruntẹlẹ ni awọn o mọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa o si ya awọn lẹnu lori ẹsun ti obinrin naa fi n kan awọn ara adugbo lori ijamba to ṣe e.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa bo ṣe jẹ pe obinrin naa ti lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Abamẹta sọ pe nnkan bii aago mẹwaa alẹ lọjọ Keji, osu Kiini, ọdun 2026 ni Arabinrin T A, Olorisa lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa Ọja Ọba, ilu Ilorin pe awọn kan sọ ina sile oun.

Ejire-Adeyemi ni obinrin naa sọ pe nnkan bii irọlẹ aago meje ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti oun ko si nile.

O ṣalaye pe obinrin naa sọ fun awọn ọlọpaa pe ninu osu Kọkanla ọdun to kọja ni awọn mẹta kan ti n dunkoko mọ oun nitori ẹsin ti oun n ṣe.

O ni awọn mẹtẹẹta naa ni Alhaji Abubakar Saliu, ẹni ọdun mejidinlọgọta, Alhaji Saliu Saka, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, Alhaji Yẹkini Ọlọruntẹlẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni awọn mẹtẹẹta naaa ti wa ni ahamọ ajọ ọlọpaa fun ifọrọwanilẹnuwo.

O ni igbesẹ n lọ lati ṣewadii ohun to ṣokunfa ijamba ina naa ati lati fidii ootọ mulẹ lori iṣẹlẹ naa.

Alukoro ajọ ọlọpaa ni kosi ẹmi kankan to sofo nibi iṣẹlẹ naa, sugbọn dukia bajẹ ti wọn o ti le sọ iye rẹ.

O fi kun pe ajọ ọlọpaa wà lati daabobo gbogbo ara ilu, ti gbogbo eeyan si ni ẹtọ lati ṣe ẹsin to ba wu wọn.