Letter to Khadija: Bàbá Khadija, ọmọ ọdún méjì tí wọn jí gbé lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn, kọ lẹ́tà ìdárò nípa ọmọ rẹ̀ sórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, UMAR SULAIMAN
Manigbagbe lọjọ ọjọ Kẹrindinlogun osu Kọkanla ọdun 2016 jẹ ninu igbesi aye Umar Suleiman ati iyawo rẹ Amina.
Lọjọ yii ni wọn foju kan ọmọ wọn Khadijat, ọmọ ọdun meji kẹyin, o si ti pe ọdun marun bayi ti Khadija ti di awati.
Ni iranti ọmọ yii, Umar kọ lẹta idaro soju opo Facebook, ti o si di nkan tawọn eeyan n ran lẹnu.
- Baba Suwe ti kú tipẹ́ ṣaájú kí gbogbo èèyàn tó mọ̀ - Àbúrò olóògbé
- Wo àwọn gbajúmọ̀ aláwàdà Yorùbá méje tó ti kú saájú Baba Suwe
- Bí DSS, DIA ṣe mú Igboho ati Kanu fihàn pé wọn kájúẹ̀ - Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
- Bàyìí ni èmi àti Abdulsalami ṣe ṣiṣẹ́ pọ̀ ba èròngbà sáà kẹta Obasanjo jẹ́ - Thabo Mbeki
- Èèmọ! Kí ló mú àwọn akẹ́kòó gírámà fìkanra dá bàǹtẹ́ ìyà fún DPO ọlọ́pàá l‘Ogun?
Ninu ifọrọwerọ, to ba BBC sọrọ nipa ọgbẹ ọkan yii to jẹ ẹdun ọkan nla fun oun ati iyawo rẹ, n se lo n fojojumọ sunkun.
Ninu iwe to kọ naa, Suleiman sọ pe ọdun marun un to kọja lọ, ko rọrun fun idile oun lai si ọmọ pẹlu awọn sugbọn awọn n gba ladura pe ki eledua fọwọ kan ọkan awọn to ji ọmọ naa gbe, ki wọn si tu silẹ''

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Suleiman tun sọ nipa bawọn se n se idaro ọmọ naa ninu lẹta to kọ yii.
Bakan naa lo sọ fun BBC pe ko si igba kan tawọn ko ranti ọmọ yii.
"Ọgbẹ yii dabi ẹni pe o sẹsẹ sẹlẹ lọkan wa ni. Ko si igba ti emi ati iyawo mi kii ranti Khadija''
''Gbogbo igba ni mo maa n ranti asiko ta lo kẹyin, to di mọ mi gbagi, to si dagbere o dabọ, bi mo ti se n lọ si ibisẹ laarọ ọjọ naa''
Suleiman Umar to kọ iwe yii ni oun lero pe o seese ki ẹni to ba ji ọmọ naa gbe, ri iwe oun, ko si yii ọkan pada lati tu ọmọ naa silẹ.
"Mo ti pari gbogbo igbiyanju mi lọdọ awọn ọlọpaa ati ajọ NAPTIP. Eyi to ku ni pe ki eeyan kan ri lẹta mi loju opo ayelujara ko si se iranlọwọ fun mi lati le ri ọmọ mi pada''

Oríṣun àwòrán, UMAR SULAIMAN
Bawo ni isẹlẹ ijigbe se waye ti Khadija fi di awati?
Agbegbe Kuje ni Abuja ni olu ilu ilẹ Naijiria ni ijinigbe yii ti waye.
"Ko si iyatọ lọjọ yii si ọjọ miran ta ti n lo tẹlẹ. Mo mura ibisẹ, iyawo mi to si loyun fẹ lọ si ile iwosan lọjọ naa.
Tori naa, o gbe Khadija lọ si ile taa n gbe tẹlẹ nibi ti awọn ọrẹ rẹ wa, ko le maa bawọn sere''
Suleiman tẹsiwaju pe ''N se lo tẹle awọn ọmọ yoku lati lọ ra nkan ni sọọbu kan ni tosi. Gẹgẹ bi ọmọ ọdun meje kan ti Khadija tẹle, wọn pade obinrin kan to beere orukọ wọn, to si ra bisiki fun wọn pẹlu ẹlẹrindodo.''
O ni obinrin naa wa sọ pe kawọn niso nile, wi pe oun yoo mu Khadija wa ba wọn Umar ni bi ọmọdekunrin naa se pada de ile lo sọ nkan to sẹlẹ.
Ka to wi ka to fọ, obinrin naa ti poora. Koda awọn eeyan kan sọ pe awọn ri pẹlu Khadija amọ awọn ko mọ pe gbọmọgbọmọ ni.

Oríṣun àwòrán, UMAR SULAIMAN
Iyawo mi maa n la alakala tori Khadija to sọnu:
Umar ni nnkan bi ago mejila ọsan ni oun gba ipe nibi isẹ ati pe lati igba naa si ni nkan ko ti jọra mọ titi di asiko yii fun oun.
"Ko si nkan ti mi o se tan.A lọ si ọdọ ọlọpaa ati NAPTIP to ni ki n kọ iwe sawọn sugbọn titi di asiko yi,wọn o se nkankan.
"Laarin kan, awọn gbajuẹ kan sọ pe ki n mu owo wa pe ọdọ awọn ni ọmọ miwa sugbọn nigba ti ọwọ tẹ wọn, a ri pe irọ ni wọn n pa''
Umar bi ọmọ meji mii lati igba ti wọn ti ji Khadija gbe.Abdulsalam to jẹ ọmọ ọdun marun un ati Salahudeen to jẹ ọmọ ọdun meji.
Amọ o sọ pe sise ayajọ ọjọ ibi ni idile awọn nira pupọ́ nitori aisinile Khadija.
O ni iyawo oun kii ye ma la alakala lori ọrọ Khadijaati pe oyun Abdulsalam to bi lẹyin igba naa fẹ ẹ bajẹ mọ lara nitori ironu Khadija to sọnu.
Lakotan Umar ni bi Khadija ba pada de loni, oun yoo pa maalu lati fi sajọyọ ipadabọ rẹ.
O wa kesi gbogbo awọn alasẹ lati dakun dabọ sawari Khadija ati awọn ọmọ miran ti wọn ji gbe.
Isẹlẹ gbọmọgbọmọ jẹ eleyi to gbogo lawujọ ni Naijiria.
Ko si si apa orileede yi kankan to moribọ lọwọ awọn alaburu to maa n pa awọn obi lẹkun lori ọmọ wọn.
Isẹlẹ gbọgbọmọ ni Naijiria di tọrọ fọn kale:
O soro diẹ lati sọ pato iye ọmọ tawọn gbọmọ gbọmọ ti jin gbe ni Naijiria nipa ijinigbe ti ko ni se pẹlu Boko Haram.
Amọ ko si ani ani pe o maa n sẹlẹ tawọn iroyin nipa rẹ si pọ daada.
Losu Kẹwa ọdun 2020 bi a ko ba gbagbe, ile ẹjọ giga ni Akure ran pasitọ Sotitobire Bababtunde ati awọn marun un miran lẹwọn gbere lori ẹsun gbọmọgbọmọ.
Alfa Babatunde yi ni wọn fẹsun kan pe o mọ nipa ijinigbe ọmọdekunrin kan Gold Kolawole to poora nile ijọsin rẹ lọdun 2019.
Lọjọ keji osu Kẹjọ 2021,arabinrin Bilikisu Salisu naa ko agbako lọwọ awọn gbọmọgbọmọ.
O ni wọn ji ọmọ oun Kusina Salisu ọmọ ọdun mẹta gbe ni adugbo Dakwa ka to de DeiDei nilu Abuja.
O ni oun ran ọmọ naa ati ẹgbọn rẹ pe ki wọn lọ ra ata toun yoo fi se ounjẹ ni .
O ni bi wọn se pada de to loun fẹ lọ sere ni nkan bi ago marun un si mẹfa irọlẹ ni oun ko ri mọ.
Laipẹ yi bakan naa lawọn abiyamọ kan se iwọde ni Kano lati fẹhonu han lori awọn ọmọ wọn ti awọn ajinigbe gbe salọ.
Wọn lawọn ko dunnu si bi ijọba ati awọn alasẹ ko se ya si ọrọ awọn ọmọ mejidinlọgọfa to di awati naa.



















