EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé torí ìwọ́de

Àkọlé fídíò, EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé àmọ́ torí ìwọ́de

Ni ọdun 2020 to kọja ni iwọde EndSARS waye jake jado orilẹede yii amọ atubọtan rẹ ko tii kasẹ nilẹ nitori awọn idile kan to wa nipo ibanujẹ lọwọ-lọwọ nitori rẹ.

BBC Yoruba se alabapade awọn idile mẹta kan ti wọn ni awọn ọlọpaa lo wa loru lati wa ko awọn ọmọ wọn nitori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iwọde EndSARS.

Nigba ti wọn n sọ bi ọrọ naa se waye, awọn mọlẹbi yii ni aarin oru ni awọn agbofinro de pẹlu ibọn sile wọn lati wa ko awọn gende naa lati ọdun kan sẹyin, ti wọn ko si ri wọn mọ.

Koda, wọn ni meji ninu awọn iya awọn ọmọkunrin naa lo ti jade laye nitori isẹlẹ yii, ti awọn baba wọn si ti dubulẹ aisan lori ọrọ naa.

Awọn mọlẹbi naa ni gbogbo igbiyanju awọn lati gba idande awọn ọmọ naa lo ja si pabo, ti awọn ọmọ eyi to ti ni iyawo ninu wọn ko si le lọ sile ẹkọ mọ.

Amọ gbogbo iyanju BBC Yoruba lati ba ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọrọ lori isẹlẹ naa lo ja si pabo.