#EndSARS: Ìpínlẹ̀ Eko fi oṣù mẹ́ta kún ìjọ̀kó àwọn tó ń gbẹ́sùn ìṣekúpani lásìkò ìwóde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ijọba ipinlẹ Eko ti fi oṣu mẹta kun iye ọjọ ti Ajọ to n gbẹjọ ẹsun iwa ifiyajẹni lọna aitọ ati iṣekupani lkẹyin iwọde ifẹhọnuhan Endsars.
Alaga Ajọ naa, Doris Okuwobi lo sọ bẹẹ lasiko ijoko ajọ naa ni opin ọṣẹ.
Ajọ naa ni ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lati gbọ ọrọ lati ẹnu awọn to fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ọtẹlẹmuyẹ SARS, ti ijọba ti tuka bayii.
Oṣu mẹfa lo yẹ ki ajọ naa fi joko ko to di wi pe wọn sun si iwaju di Ọjọ Kọkandinlogun, Osu Kẹrin kẹrin, odun 2021.
Ti wọn tun sun fun igba keji fun oṣu mẹta di oṣu keje, ọdun 2021, ki wọn tun ṣẹṣẹ sun bayii fun oṣu mẹta miran.
Lasiko ti alaga naa n sọrọ, ni igbẹjọ ti awọn ri gba jẹ marundinlogojilenigba(235), amọ mẹrindinlaadoje pere ni awọn ti sagbeyẹwo rẹ.

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ti pariga kuro ninu ajọ naa lẹyin ti ayẹwọ ti ileewosan Reddington gbe jade ni lootọ ni awọn afẹhọnuhan EndSARS to waye ni Oṣu kẹwa, ogunjo, ọjọ kọkanlelogun ati ikejidinlogun, ti wọn gbe wa si ileewosan naa ni ọta ibọn lara.
- Iléẹjoọ́ feẹ̀sùn kan ìyá 'deacon' pé ó lu ọ̀gá reẹ̀ ní jìbìtì
- Wo awọn ‘Apps’ to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ
- Ìpànìyàn àti ìjínigbé tó gẹ́ ni Southern Kaduna, El-Rufai wá ń ke se-Ọ̀dọ́ Kaduna
- Ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù
- Ìjọba àpapọ̀ tún ti kébòsí lórí Sunday Igboho, wọ́n ní ó ń gbìyànjú àti sá kúrò ní Nàìjíríà
Lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ ni awọn eniyan ti wọn ti fẹsun kan yii ti gba owo ''gba mabinu'' lẹyin ifọrọwanilẹnuwo ati iwadii naa.
O ti le ni ọgbọn miliọnu naira ti wọn ti fun awọn eniyan to lugbadi ikọlu awọn otẹlẹmuyẹ ati ọlọpaa kogberegbe SARS, ti ijọba tuka lẹyin iwọde ENDSARS.












