Flood: O kéré tán ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù

Flood: O kéré tán ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù

Ẹni eegun ń lé kó máa rójú ni o, bi ó ti n rẹ ara aye lo n rẹ ara ọ̀run.

Èyí ló dífá fún òjò tó rọ̀rọ̀rọ̀ tó fẹ́ẹ̀ wú òkú slẹ́ nílùú Eko lánà àti àwọn apá ìbìkà ní ìpínlẹ̀ Ogun tó fi mọ́ ìlú Abuja.

Kìí ṣe Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkàn ni ọ̀rọ̀ náà kàn o, kódà ó mú èmí ènìyàn tó lé ni ẹgbẹ̀rín lọ ní orílẹ̀-èdè Germany, tó sì lé ọ̀pọ̀ kúrò ní ibùgbé wọn.

Sáájú àsìkò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn fọ́ran tí n jẹyọ lórí ayélujára bí omíyale àgbàra ya sọọbù náà ṣe ń gbalẹ̀ ní ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì láti ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Ìròyìn sọ pé ní orílẹ̀-èdè Germany, West Germany ni ọ̀rọ̀ náà kàn jùlọ, eyí tí àwọn odò ya wọ ìfgborò tí ọ̀pọ̀ ilé sì rì sí abẹ́ omi.

Belgium bákan náà ti fi léde pé ènìyàn méjìlá ló ti dèrò ọ̀rún níbí ọ̀rọ̀ omíyalé tó ṣẹ̀lẹ̀ níbẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn adarí ìlú àti àwọn olóṣèlú ló dẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru ìsòrò ọ̀rọ̀ ojú ọjọ́ tó n yí padà.

Ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ní ìpińlẹ̀ Eko bákan náà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà òjò yìí tí ṣe àkọ́bá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.

Ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù

Ọ̀pọ̀ àwọn fọ́ràn tó jẹyọ lójú òpó ayélujara fi hàn pé ọ̀pọ̀ mótò ló rì sómí.

Òjò náà kò da mọ ni apá kan ní Eko gbogbo ìpínlẹ̀ Eko lo mì tìtì pẹ̀lú àgbàrá òjò náà.

Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó n mójú tó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì (NEMA) ti rọ gbogbo àwọn ará ìlú láti máa ṣe àwọn nǹkan tó tó ni àdúgbò àti àyíká wọn

Amugbálẹ́gbẹ́ẹ̀ NEMA fún ẹkun South- South Ibrahim Farinloye sàlàyé pé kí ará ilu dẹ́kun láti máa rin lásìkò tí òjò ń rọ, pàápàá jùlọ tí omí bá ti bo ìdájì tíre mótò.

Ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù

Oríṣun àwòrán, Reuters