NYSC Anthem: Omijé bọ́ lójú alàgbà Adetiran tó kọ orin àkọmọ̀nà NYSC ní Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, other
Ọmọwe Oluwọle Adetiran ẹni ọdun mẹrinlelaadọta to ṣe agbekalẹ orin akọmọna ajọ agunbanirọ orilẹede Naijiria, NYSC bu gbamu si ẹkun l'Ọjọbọ ti oludari agba ajọ naa, ọgagun Shuaibu Ibrahim bẹl wo ni ile rẹ to wa ni agbegbe Ibafo ni ipinlẹ Ogun.
Ẹ lee maa wo pe ki lo lee faa ti agbalagba fi n bu si ẹkun laarin ọpọ eniyan?
Baba Adetiran to gbe orin naa kalẹ ni ọdun 1984 ni ohun to n pa oun lẹkun ni pe lẹyin ọdun mẹtadinlogoji, wọn ṣi iwe iranti kan oun.
- Àwọn agbébọn tún ti pa ọ̀gágun àgbà 'Major General' kan ní Nàìjíríà
- Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria tu ẹgbẹ̀rún kan afurasí Boko Haram sílẹ̀ ní àhámọ́
- Wo àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ṣe pàṣípààrọ̀ ìyàwó wọn nítorí ìfẹ́
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ìjọba Naijiria kéde ọjọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú tó n bọ̀ fún ìsinmi ọdún Ileya
O ṣalaye pe aisan ẹjẹ riru, itọ ṣuga ati jẹjẹrẹ lo n ba oun finra lọwọ bayii
O ni ọdun 1984 ti oun n sinru ilu ni ipinlẹ Ọyọ ni oun ks orin naa.
Ọmọwe Adeniran ko ṣai kan sara si oludari ajọ naa fun ẹyẹ nla to ni o ṣe fun oun pẹlu abẹwo naa.
Ninu ọrọ rẹ, oludari agba fun ajọ NYSC lorilẹede Naijiria, Ọgagun Ibrahim ni ọmọ Naijiria to ṣee fọkansin ni alagba Adetiran ti ẹnikẹni ko lee ko iyan rẹ kere, paapaajulọ ipa rẹ ninu idagbasoke ajọ agunbanirọ orilẹede Naijiria.








