Yoruba Nation: Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Aderemilekun Adeoluwa Omojola, agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC

Oríṣun àwòrán, Jersey City Free Public Library
Ọjọru, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun un, ọdun yii ni Sunday Igboho, Ọjọgbọn Banji Akintoye atawọn míràn fa Aarẹ Buhari, Malami àtàwọn míì lọ síwájú ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC.
Ile ẹjọ naa si ti da esi pada fun awọn olupẹjọ pe oun ti gba iwe ẹbẹ ti wọn kọ ranṣẹ, ati pe oun yoo yẹ ẹjọ naa wo.
Ẹsun ipaniyan ati ifiyajẹ ọmọ eniyan ni wọn fi kan aarẹ Buhari ati Malami pẹlu bi wọn ṣe pa lara awọn ajijagbara fun Ilẹ Yoruba ati awọn miran.
- Cubana Chief Priest ra màálù 46 fún ìsìnkú ìyá ọ̀gá rẹ̀, àwọn ọmọ Naijiria ń fi èrò wọn hàn
- Ẹ wo ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Tolulope Arotile
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Bí ọkọ mi ṣe fi ẹ̀wọ̀n irin dè mí mọ́ bẹ́ẹ̀dí tó fipà bá mi lòpọ̀ títí oyún fi bàjẹ́ lára mi'
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo bere pe ta ni agbẹjọro to wa nidii ipẹj yii?
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa agbẹjọro naa ree:
- Orukọ agbẹjọro naa ni Aderemilekun Adeoluwa Omojola
- Ilu Amẹrika lo fi ṣebugbe.
- Iṣẹ agbẹjọro gbogbogbo ni Omojola n ṣe amọ o ni imọ to danto nipa ọrọ to jọ mọ mọlẹbi, tita ati rira ileegbe, owo ṣiṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Omijola kẹkọọ gboye nipa eto oṣelu ni New Jersy City University, NJCU
- Agbẹjọro naa tun kawe gboye ni Seton Hall University School of Law, nibi to ti gba oye Juris Doctor
- Omojola ni oludislẹ ati adari ile iṣẹ awọn amofin, Omojola & Associates, P.C. to wa niluu New Jersy, l'Amerika
- Oṣu Keji ọdun 2012 ni Omojola ti n tukọ ile iṣẹ naa bọ, eyii to n tumọ si pe o ti le ni ọdun mẹsan an bayii





















