Igboho, Akintoye, Yoruba Nation pe ẹ̀sùn mọ́ Buhari, Malami àtàwọn míì ní Kóótù `ọdaràn `Agbáyè, ICC

ICC

Oríṣun àwòrán, Atlantic Council

Ẹsun ipaniyan ati ifiyajẹ ọmọ eniyan ni wọn fi kan aarẹ Buhari ati Malami pẹlu bi wọn ṣe pa lara awọn ajijagbara fun Ilẹ Yoruba ati awọn miran.

Ileẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ọdaran lagbaye, ICC ti fi lede pe awọn ti gba iwe ẹsun ti adari Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye, Sunday Igboho ati awọn ajijagbara mọkandinlaadọta miran pe mọ ijọba Naijiria ati awọn adari.

Ile ẹjọ ICC ti fi atẹjade sita pe wọn ti bẹrẹ iwadii nipa ẹjọ naa bayii.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, @TheNationNews

A ti gba ẹ̀sùn tí ẹ fi kan Buhari, Malami, Buratai wọlé - Kóótù `ọdaràn l'ágbáyè, ICC

Ẹjọ naa ni wọn pe mọ Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari , minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami, adari ikọ ọmọogun Naijiria, Tukur Buratai ati ọga ọlọpaa agba tẹlẹri, Ibrahim Idris ati Muhammadu Adamu.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Lara awọn adari miran ti wọn pe ni ẹjọ ni Hammid Alli, Alkali Baba, Farouk Yahaya, Sadiq Abubakar, Ahmed Abubakar Audi, Mohammed Babandede ati Abdulahi Gana Muhammadu.

Ninu atẹjade ti ileẹjọ ICC lagbaye fi ṣọwọ pada si wọn ni wọn ti fi lede wi pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan awọn adari yii ni ẹyọ kọọkan.

Ẹsun ipaniyan ati ifiyajẹ ọmọ eniyan ni wọn fi kan aarẹ Buhari ati Malami pẹlu bi wọn ṣe pa lara awọn ajijagbara fun Ilẹ Yoruba ati awọn miran.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y

Bakan naa ni wọn fẹsun kan awọn wọnyii pe wọn lọwọ ninu ọrọ ipaniyan, dida awọn ọmọ Naijiria pada lati oke okun lọna aitọ.

Lara ẹsun ti wọn tun fi kan wọn ni ifiyajẹ ọmọniyan lọna aitọ, ijinigbe ati ifipabanilopọ eleyii ti wọn ko ri iru rẹ ri.