Ladipo Spare parts Market: `ijọba ìpínlẹ̀ Eko ti ti Ọjà Ladipo pa

Awọn alaṣẹ ti ile itaja naa lati tako ifẹhọnuhan to waye ni ọja naa ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Keje, ọdun 2021.
Awọn alaṣẹ ti ti ọja Ladipo ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ pa ni ipinlẹ Eko, lorilẹede Naijiria.
Awọn ọlọja ni ọja naa lo kọlu awọn soja, amọ ko si ẹni to le e sọ ohun to fa ija wọn.
Ọkan lara awọn ọlọja nibẹ sọ fun BBC pe ẹmi eniyan kan lọ si iṣẹlẹ naa, ti awọn mẹta to farapa si wa ni ileewosan.
Awọn alaṣẹ ti ile itaja naa lati tako ifẹhọnuhan to waye ni ọja naa ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹrinla, Oṣu Keje, ọdun 2021.

Ọja Ladipo ni ọja kan pato ti wọn ti n ta ẹya ara oko ni ipinlẹ Eko nitori ko si ọkọ to yọnu ni ilu Eko ti kii ṣe ọja Ladipo ni wọn ma n gbe lọ.
Awọn ti ọrọ naa ṣẹlẹ ni oju wọn sọ wi pe ohun to fa ija ni awọn onibara to wa ra ọja ni ibẹ, amọ to wa da pada ni ọjọ keji pe ko dara.
Eleyii ko ba ọlọja naa lara, to si fa ija, eleyii to mu ki onibara naa lo mu awọn soja wa, ti wọn si wa da ibẹ ru.
Iroyin nipe awọn ọmọogun ofurufu lo wa sibẹ lati wa fa rogbodiyan naa.
Titi di asiko yii, ọja naa wa ni titi pa.
Gbẹgẹdẹ tun gbina laarin awọn ọmọ ologun atawọn ọmọ ọraẹsa to n ja tikẹẹti lọja Ladipọ nilu Eko lọjọ Iṣẹgun
Lasiko ti a kọkọ ti a kọkọ ko iroyin yii jọ, awọn eeyan kan ti jade laye nipasẹ iṣẹlẹ ọhun.
Awọn eeyan kan n fi iye awọn to ku si mẹta nigba ti awọn miran n sọ pe marun un ni wọn.
- Mr. Portable sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Mr. Latin lórí gbas-gbos tó ń wáyé lágbo òṣèré tíátà Yoruba
- Gbàgbé ẹ! Ìjọba kò lè yọwọ nínú fifi ọba jẹ láéláé- Oba Tejuosho
- Àwọn Aṣòfin yọwọ́ nínú àbádòfin tí yóò máa fòfin de àwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀hónúhàn
- Ìjọba Gombe kọ́ iléẹ̀kọ́ tuntun sí ẹgbẹ́ àwọn iléeṣẹ́ elétò aàbò kí ọwọ́ ajínigbé má tẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ mọ́
- 'Lóòtọ́ èmi ni mo ṣagbátẹrù òpó alátagbà Airtel lọ sí Ago Owu ṣùgbọ́n kìí ṣe àkànṣe iṣẹ́ agbègbè mi'
Gẹgẹ bi oniṣowo kan lọja naa ṣe sọ, "Awọn ṣọja kan wa sibi ni wọn si bẹrẹ si ni yinbọn si wa."
Gẹgẹ bi iroyin tun ṣe fi idi rẹ mulẹ, ọpọlọpọ lo ṣeṣe.
Iroyin abẹle fidi rẹ mulẹ pe ija naa bẹẹ silẹ laarin awọn ọmọ ogun ikọ alaabo Operation MESA atawọn janduku kan lagbegbe naa ti wọn n ja tikẹẹti. Eyi lo ṣokunfa bi awọn ọmọ ogun ṣe ṣi ina ibọn bolẹ.
Bakan naa lawọn kan tun sọ pe, oṣiṣẹ ileeṣẹ ọmọogun ofurufu NAF kan lo yinbọn lẹyin edeaiyede kan pẹlu awọn oniṣowo kan nibẹ lori ọja kan to ra.
Ija bẹ silẹ lọmọ ogun naa ba rasnṣẹ pe awọn akẹgbẹ rẹ.
Amọṣa agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu, Ọgagun Edward Gabwet ṣalaye fawọn oniroyin kan pe ipe pajawiri kan lawọn ọmọ ogun ti wọn wa ni ikọ Operation MESA gbọ ti wọn lọ dahun si pe wahala kan bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ogun oriilẹ kan ati ajigbese kan.
Lọja lawọn oniṣowo kan ti kọlu wọn pẹlu okuta.
Bakan naa lawọn ọmọogun oriilẹ ni iwadi ti nlọ lori iṣẹlẹ naa.
- Wọ́n ti yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún Baba Ijesha ní Ireland kúrò lórí ayélujára
- Wo òtítọ́ nípa oúnjẹ Nódùùlù táwọn ọmọde máa ń jẹ
- Gbogbo owó àjẹmọ́nú ti mo ti gbà láti 2017 ni màá dá padà fún ìjọba- Ìyàwó aarẹ Ghana
- Èèyàn 2,371 ni wọ́n jí gbé, N10biliọnu owó ìtúsílẹ̀ làwọn ajínigbé gbà lóṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2021
- Mo gbọ́ pé babaláwo mẹ́ta ló tẹ̀lé àwọn DSS lọ sí ilé Sunday Igboho- Gani Adams
- Gbàgbé ẹ! Ìjọba kò lè yọwọ nínú fifi ọba jẹ láéláé- Oba Tejuosho

















