Ekiti rape case: Ẹ̀ṣọ́ ìyàwó Gómìnà Ekiti Bisi Fayemi bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ l'Abuja

Kayode Fayemi ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/KAYODE FAYEMI

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileeṣẹ ọlọpaa olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja ti fi ọwọ sinkun ofin mu ọkan lara awọn ẹṣọ iyawo gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayemi.

Ẹsun ti wọn fi kan ẹṣọ naa ni pe o fipa ba obinrin lopọ niluu Abuja lọjọ karun un oṣu keje.

Kọmiṣọnna eto idajọ ipinlẹ Ekti, Olawale Fapohunda lo fọrọ naa lede loju opo Facebook ipinlẹ Ekiti.

Fapohunda ṣalaye pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Abuja to n ri si ẹsun iwa ọdaran ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Kọmiṣọnna eto idajọ ipinlẹ Ekti sọ pe ipinlẹ Ekiti yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa Abuja lori iṣẹ iwadii wọn.

''Ọmọbinrin ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si ti n gba itọju ati atilẹyin to nilo bayii.

Bakan naa a ko fẹ ki ẹnikẹni mọ ọmọbinrin naa lati le daabo bo o ki o maa ba di ojuti fun un.

Ijọba Ọmọwe Kayode Fayemi yoo maa tẹsiwaju lati tako iwa ifipabanilopọ nipinlẹ Ekiti.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Amọ, ijọba nilo iranlọwọ awọn araalu lati maa sọrọ soke lori iwa ifipabanilopọ ki ijọba le gbe igbesẹ ni kiakia.

Ajumọṣe gbogbo wa ni ọrọ ti o wa nilẹ yii,'' Fapohunda lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ekiti ti gbe eeyan mọkanlelọgọfa lọ si ileẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ.

Kọmiṣọnna eto idajọ ipinlẹ Ekti ni igbẹjọ ti n lọ lọwọ lori awọn ẹsun naa.

O fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan ti ẹbi wọn sẹtan lati gbaruku ti ijọba lori ṣiṣe ẹjọ ni ijọba n ṣe ẹjọ wọn.