Sunday Igboho: Gani Adams ní àwọn tó yí Igboho ká ló ṣíṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú DSS tó kọlu ilé rẹ̀

Aarẹ Gani Adams pẹlu Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Gani Adams ati Sunday Igboho

Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba ganu Adams ti sọ pe awọn eeyan to sun mọ Sunday Igboho lo maa jẹ ko rọrun fawọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati ṣe ikọlu si ile rẹ lagbegbe Soka niluu Ibadan.

Aarẹ ni Ọlọrun n bẹ bi ti atijọ, awọn eeyan ni ko sin Baba bi ti atijọ mọ.

Gani Adams ni oogun si wa nilẹ Yoruba bi ti atijọ, ṣugbọn bi awọn ajijagbara ṣe n ṣe nkan si ara wọn lawọn agbofinro naa n ṣe.

Aarẹ ni awọn ọmọ Yoruba naa lo n ṣe oogun fawọn agbofinro.

''Gẹgẹ bi ohun tawọn eeyan n sọ, ohun ti mo gbọ ni pe babalawo mẹta lo tẹle awọn ajọ DSS lọ ṣe ikọlu si ile Igboho loru.

Ohun ti mo gbọ nio, mi o mọ bo ya otitọ ni tabi irọ.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Nigba ti wọn jade tan, ẹnikan tun pe wọn pe ki wọn lọ ko awọn ologbo rẹ.

Wọn ro pe bo ya awọn ologbo yẹn lo fi n ṣe agbara, eyi tumọ si pe awọn to yi Sunday Igboho ka lo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn DSS lati mu un.

Wọn tun pa eeyan bii meje nile rẹ ṣugbọn wọn ni meji lawọn pa.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Ṣugbọn ati oku ati aye awọn ti wọn pa wọn gbe gbogbo wọn lọ.

Oku awọn adigunjale nikan ni awọn agbofinro lẹtọọ lati gbe lọ kii ṣe okun awọn ajijagbara.

Àkọlé fídíò, Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua

Ohun to buru pupọ ni, gbogbo awa ọmọ Yoruba ni a bu ẹnu atẹ lu bi ajọ DSS ṣe kọlu ile Sunday Igboho,'' Gani Adams lo ṣalaye bẹẹ.

O ni Igboho tẹlẹ gira gira diẹ pẹlu awọn iwọde to ṣe lori ipe fun idasilẹ Yoruba, amọ agba wa bura bi ewe o ba ṣe ọ ri ni ọrọ Igboho.

Aarẹ ko bẹsu bẹgba lati sọ pe oun si wa lori ẹsẹ oun lori idasilẹ Yoruba Nation.

Àkọlé fídíò, Royal Hugs Surprises: Ìyá ẹni ọdún 50 tó dọlọ́mọ láyé fi ìdùnnú hàn bí a ṣe kàn síi- Debor