Awujale: Àlàáfíà ni Ọba Sikiru Adetona wà ní ààfin rẹ̀- Alaga Kamorudeen ti Ijẹbu Ode tó jẹ́ adarí ètò Ojude Oba

Awujale

Oríṣun àwòrán, Funmilayo Sdff Oluwaseundavid

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati aafin Awujale ti ilẹ Ijebu, Ọba Sikiru Adetona sọ pe Kabiesi ko tii waja gẹgẹ bi iroyin ti awọn eeyan ka n gbe kiri lori ayelujara.

Ọkan lara awọn eeyan to sumọ ori ade naa, Alhaji Alaga Kamorudeen, to jẹ adari eto ọdun Ojude Oba ti ilẹ Ijebu ṣalaye fun BBC Yoruba pe alaafia ni baba wa ni aafin rẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni oun ṣi foju ganni Kabiesi ni nnkan bi ọjọ meji sẹyin.

Kamorudeen ni "Ẹ ma naani iroyin ti awọn kan n gbe kiri lori ayelujara, ko si nnkankan to ṣe baba o."

"Mo ṣi wa lọdọ Kabiesi lọjọ Aiku lati nnkan bii aago mejila ọsan titi di alẹ ni aafin wọn ko sì sí nnkankan to ṣe wọn."

Awujale

Oríṣun àwòrán, JOJO TV

"Ipade meji ni wọn ṣe lọjọ naa, lẹyin ti mo ba wọn ṣe ipade tan, wọn tun ba awọn ọba meji miran ṣe ipade."

Kamorudeen sọ siwaju si pe oun naa ti gbọ iroyin ọhun pe kabiesi ti waja, irọ patapata ni iroyin naa jẹ.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Alaga tun ṣalaye pe ko ni si ọdun Ojude Ọba lọdun yii bi wọn ṣe maa n ṣe tẹlẹ latẹyinwa.

Ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun 1960 ni Ọba Sikiru Kayode Adetona gori itẹ gẹgẹ bii Awujale ilẹ Ijebu.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams