Sunday Igboho's Yoruba Nation rally: Ẹ máa retí ìdájọ́ àwọn olùwọ́de Yoruba Nation tó wà láhàmọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa Eko gbe ẹjọ awọn oluwọde to ṣe Yoruba Nation Rally nipinlẹ Eko lọjọ Abamẹta to kọja wa siwaju ile ẹjọ.
Awọn agbofinro ni wọn gbe igbesẹ yii lati faṣẹ si dide awọn oluwọde naa mọ ahamọ fun ọjọ mọkanlelogun.
Ile ẹjọ majisireeti kan to wa ni Yaba, ipinlẹ Eko ti ni awọn o gba ki wọn gba beeli awọn oluwọde mọkandiladọta ti Ọlọpaa mu nigba iwọde Yoruba Nation to waye nipinlẹ Eko laipẹ yii.
Ọjọ mọkanlelogun ni aṣẹ ti wọn gba lati fi ko awọn ti wọn mu yii si ahamọ.
Adajọ ile ẹjọ naa, Arabinrin Adeola Adedayo paṣẹ pe ki wọ́n dari ẹjọ naa lọ si ẹka idajọ ọrọ ilu ni ipinlẹ Eko fun imọran to kan ofin.
- Wọ́n ti yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún Baba Ijesha ní Ireland kúrò lórí ayélujára
- Wo aya tuntun tí Balogun Super Eagles, Ahmed Musa fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó kẹta
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Ìròyìn ayọ̀! Emir tí wọ́n jígbé ní Kaduna gba ìtúsílẹ̀, báwó ló ṣe ṣeé láàrin ọ́jọ́ méjì?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kéde òní ọjọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi nítorí ikú ìgbákejì gómìnà Bantex tó dolóògbé
A ò gba béèlì!
'Ẹ wòó, ẹ máa retí ìdájọ́ àwọn olùwọ́de Yoruba Nation 49 tó wà láhàmọ́ Ọlọ́pàá ní ọjọ́ ...'
Ni agbegbe Ọjọta, ipinlẹ Eko ni wọn ti fi panpẹ ọba mu awọn mọkandinlaadọta ọhun lọjọ kẹta oṣu keje nigba ti wọn n wọde fun gbigba orilẹede Oduduwa.
Aba fun gbigba beeli wọn eyi ti awọn agbẹjọro ajafẹtọ ọmọniyan kan eyi ti Olasupo Ojo ati Oladapo Kayode dari ni wọn ti sun siwaju di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje ọdun 2021 bayii fun igbẹjọ mii.
- Ìwà àbùkù tí kò bá ojú mu ni Yomi Fabiyi àti Dele Matti hù pẹ̀lú eré Ọkọ Iyabọ- TAMPAN
- Ìgbìmọ̀ olùwádíì ìpínlẹ̀ Eko tẹ́wọ́ gba èsì àyẹ̀wò "Autopsy" òkú 99 tí wọ́n rí he lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi kò rọrùn rárá ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ mó di ayaba- Jaye Kuti
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Àwọn ìwé ìròyìn yarí lórí àtúnṣe tí ilé aṣòfin ń ṣe lórí òfin tó de iṣẹ́ akọ̀ròyìn
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lọ́jọ́ Aje, ọjọ karun un, ni ile ẹjọ faṣẹ si aṣẹ ofin ti ile iṣẹ ọlọpaa Eko gbe wa siwaju ile ẹjọ lati faṣẹ si dide awọn oluwọde naa mọ ahamọ fun ọjọ mọkanlelogun.
Ọjọ mọkanlelogun yii yoo kasẹ nilẹ ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2021.
- Àwọn tó jí Emir gbé ní Kaduna ti kàn sí Mọ̀lẹ́bí- Emirate Kajure
- Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí Sẹ́nétọ̀ Adelere Oriolowo, APC tó fi opó ẹ̀rọ ayélujára Airtel ṣe iṣẹ́ àkànṣe ìlú ní Osun
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Port Harcourt mú ẹ̀mí ènìyàn 5 lọ
- Wo ohun tí TuFace, Mr Macaroni àti DJ Cuppy sọ nípa Sound Sultan
- Ọlọ́pàá mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn mẹ́ta tí wọ́n fi típa mú akẹgbẹ́ wọn wọ ẹgbẹ́
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kéde òní ọjọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi nítorí ikú ìgbákejì gómìnà Bantex tó dolóògbé

















