EndSARS: Mẹ́ta lára àwọn òkú náà ni wọ́n rí he lágbègbè Lekki Toll Gate

Oríṣun àwòrán, Ken Erics Ugo
Igbimọ oluwadii iwa ipa awọn ọlọpaa si awọn araaalu ni ipinlẹ Eko ti tẹwọ gba esi ayẹwọ oku eeyan mọkandilọgọrun run ti wọn ri he kaakiri ilu Eko lasiko iwọde EndSARS.
Awọn oku naa ti wọn ti wa ni ile igbokupamọsi ni wọn ri he kaakiri ipinlẹ Eko laarin ogunjọ, oṣu Kẹwaa ọdun 2020, si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun kan naa.
Onimọ sayensi to n ṣayẹwo ara eeyan, Ọjọgbọn John Obafunwa lo fi esi naa le adari igbimọ ọhun, Adajọ Doris Okwobi lọwọ.
- Ìwà àbùkù tí kò bá ojú mu ni Yomi Fabiyi àti Dele Matti hù pẹ̀lú eré Ọkọ Iyabọ- TAMPAN
- 'Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo'
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- 'Ọkọ̀ ojúomi Noah kò gbádùn tó, làwọn ẹ̀ṣọ́ orí omi fi dèé mọ́lẹ̀ ní Ipswich''
- Ìwé ẹ̀rí àyẹ̀wò oògùn olóró yóò di dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbé'yàwò láìpẹ́- Buba Marwa NDLEA
Igbimọ naa gba awọn ẹri ọhun ti wọn ko sinu apo meji wọle lẹyin ti agbẹjọro awọn olufẹhonuhan EndSARS, Adeyinka Olumide-Fusika daba pe ki igbimọ ọhun tẹwọ gba awọn eri naa.
Awọn agbejọro atawọn ọmọ igbimọ naa si faramọ igbeṣe naa pẹlu.
Ṣaaju ni igbimọ naa ti kọkọ fiwe pe Ọjọgbọn Obafunwa lati wa ṣeranwọ fun un lori iwadii rẹ nipa iye ẹmi to sọnu lasiko iwọde EndSARS, paapaa ni iloro Lekki Toll Gate.
Laisko to kọkọ yọju siwaju igbimọ ọhun lọjọ karun un, oṣu Kẹfa ọdun yii ni igbimọ naa ni ko ko awọn eri naa wa siwaju rẹ.
Eyii to mu ki Ọjọgbọn nipa imọ eto ilera, to tun jẹ olukọ to dantọ nile ẹkọṣẹ iṣẹgun ti fasiti ijọba ipinlẹ Eko, LASU, sọ niwaju igbimọ naa pe lootọ ni awọn ti ṣiṣẹ lara awọn oku mọkandinlaadọrun un ọhun.

Oríṣun àwòrán, BBC Hausa
Gẹgẹ bi ohun ti Ọjọgbọn naa sọ, mẹta lara awọn oku naa ni wọn ri he lagbegbe lekki Toll Gate ti awọn mẹtẹta si jẹ ọkunrin, ṣugbọn awọn ko mọ irufẹ ẹni ti awọn oloogbe naa jẹ.
- Bobrisky fi àwòrán tuntun léde lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ abẹ ìdí tó ṣe
- A ń gbóhùn àdúrà sókè ní orílẹ̀èdè 127 lágbàáyé torí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Baptist tí wọ́n jígbé ní Kaduna -Baptist Convention
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- Mó ṣèlérí láti buwọ́lu àtúntò Naijiria, Ilé Aṣòfin o kù sí ọwọ́ yín - Ààrẹ́ Buhari
Ko din ni eeyan mẹrinla to ti fẹsun kan ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria atawọn ọlọpaa pe wọn yinbọn pa ọpọ awọn oluwọde EndSARS lasiko iwọde EndSARS naa.
Wọn fẹsun kan awọn agbofinro ọhun pe ọkẹ aimoye awọn miran lo farapa lasiko ti wọn ṣina ibọn bolẹ fun wọn lasiko ti wọn n ṣewọde lodi si iwa ipa awọn ọlọpaa si araalu.
Bo tilẹ jẹ ileeṣẹ ọmọ ogun sẹ pe awọn ko pa ẹnikẹni lọjọ naa lọhun, ileeṣẹ naa ti kọ lati maa yọju siwaju igbimọ naa bayii, ṣugbọn igbimọ ọhun ṣi n ba iṣẹ rẹ lọ.
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dájọ́ fún Yomi Fabiyi àti igbákejì rẹ̀ lórí fíìmù Oko Iyabo
- Yomi Fabiyi sọ̀rọ̀ sókè lóri bí TAMPAN ṣe gbé igi le lẹ́yìn
- "Kò sí Pásítọ̀ tó ṣiṣẹ́ ìyanu, tó lé ẹ̀mí èṣù jáde bíi TB Joshua"
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- Ẹ wo ọ̀nà àbáyọ tí adigunjalè bá kọ lẹ́tà sí yín pé àwọn fẹ́ ẹ́ wá jà yín lólè















