Ìwé ẹ̀rí àyẹ̀wò oògùn olóró yóò di dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbé'yàwò láìpẹ́- Buba Marwa NDLEA

Marwa

Ajọ naa ni eyi kun ara ero tuntun ti wọn n gberolatidẹkun elo ogun oloro lorilẹede Naijiria.

Ajọ to n gbogun ti ogun oloro ni Naijiria, NDLEA ni laipẹ laijina gbogbo awọn to ba fẹ ṣe igbeyawo lorilẹede Naijiria ni yoo ni lati maa gba iwe aṣẹ ọ mọ lọwọ ogun oloro ki wọn to lee ṣegbeyawo.

Alaga ajọ naa, Ọgagunfẹyinti Buba Marwa lo sọ eyi di mimọ nibi ayẹyẹ kan n'ipinle Kogi.

Ọgagun Marwa ni ipinu Aarẹ Buhari lati le ogun oloro lorilẹ-ede Naijiria ko yingbin rara.

O ni idi gan niyi ti wọn fi gbe awọn etokan silẹ ninu eyiti gbogba iwe ayẹwo ogun oloro saaju Igbeyawo gẹgẹ bi I iwe ayẹwo HIV ṣe fẹ waye.

Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

Koda o ni " Laipẹ jọjọ ẹnikẹni to ba n wa iṣẹ ijọba tabi n wa ati wọlẹ si ile ẹkọ gigaga tabi gbeyawo yoo kọkọ ni lati ṣe ayẹwo ogun oloro na."

Marwa tun salaye pe ileṣẹ NDLEA ti ri oogun oloro to le ni milionu meji kilogiraamu gba pada lọwọ awọn eeyan ni kete ti oun ti wọ iṣẹ gẹgẹ bii ọga wọn.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib