Champlain Towers South: Èèyàn 99 ni wọ́n ṣì n wá nínú ilé tó wó ní Miami

Oríṣun àwòrán, Miami Dade Fire and Rescue
O kere tan, eeyan kan ti ku, ti awọn to to mọkandinlọgọrun si di awati lẹyin ti ile alaja mejila kan, Champlain Towers wo lulẹ ni oru mọju Ọjọbọ, nilu Miami, Florida, lorilẹ-ede America.
Awọn oṣiṣẹ pajawiri si ti n wa gbogbo abẹ awoku ile naa lati ṣawari awọn to ṣe e ṣe ko wa laaye, lara awọn ti wọn ti ri awọn kan yọ sita.
- Ẹ̀bùn owó, oúnjẹ, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní ìkókó mú wọlè fún ẹbí Kemisola Ogunniyi ní Ondo
- Ẹyìn tẹ ń gba ojú VPN wọ Twitter, ẹ kò ṣé mí, ará yín lẹ̀ ń ṣé - Lai Mohammed
- Ta ló gbé ìròyìn ikú ẹlẹ́jẹ̀ nípa Wòlìí SK Abiara, kí ní wọ́n sì ṣe fún un?
- Àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Yoruba dalẹ̀ wa lórí àwọn ọmọ OPC mẹ́ta tí wọ́n tímólé láìṣẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Iskilu Wakili - Ẹgbẹ́ OPC
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ ẹni méjì tó lọ́wọ́ nínú àgbo tó pa ẹni mẹ́wàá ní Kwara
A ko ti i le sọ iye eeyan to wa ninu ile naa lasiko to wo, paapaa bo sẹ jẹ pe ile gbigbe ni.
Abala mẹta ni ile naa, to si ni aadoje ojule . Abala kan lo wo lulẹ.
Ile naa ti pe ogoji ọdun ti wọn kọ ọ.

Awọn oṣiṣẹ adoola sọ pe awọn n ṣiṣẹ karakara lati doola awọn to wa labẹ ile naa, nitori pe awọn n gburo awọn eeyan to n gba nkan labẹ àlàpà.
Katakata oloke si ni awọn oṣisẹ adoola n lo lati fi doola awọn eeyan to wa ni awọn ile to wa ni tosi ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Makinde pàṣẹ pé kí wọ́n wó iléègbé àwọn òṣìṣẹ́ BCOS ní Ibadan?
- Ṣé lóòtọ́ ni Kọmísọ̀nà Fidelis Nweze jíǹde padà? Ohun tí ìjọba sọ rèé
- Yinka Alaṣeyori fi ọ̀rọ̀ ìjínlẹ̀ púpọ̀ àti omijé ṣàlàyé Oniduro Mi
- Wo àwọn ìlànà tí ó máa tẹ̀lé láti wo èsì ìdánwò 2021 Jamb UTME rẹ lórí ayélujára àti SMS
- Ilé ẹjọ́ gba béèlì Baba Ijesha N2Miliọ̀nù ní wọ́n fún
Awọn alaṣẹ sọ pe iṣẹ idoola naa ko le ya, to si lewu nitori pe awoku ile naa le wo lulẹ le wọn lori.

Oríṣun àwòrán, Google street view
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa sọju rẹ sọ fun akọroyin CNN pe bi ile naa sẹ wo dabi iṣẹlẹ 9/11, eyi to jẹ ikọlu si World Trade Center Twin Towers nilu New York lọdun 2001.
Ẹlomii ti iṣẹlẹ naa tun ṣoju rẹ sọpe ile naa kọkọ n mì, ko to o di pe o wo lulẹ.















