Iskilu Wakili: Móríyá ní bí iléẹjọ́ ṣe tú àwọn OPC mẹ́tà sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n mú Iskilu Wakili tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn

OPC

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Ọyọ, Rotimi Olumo ti gboriyin fun idajọ otitọ lori awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta ti ileeṣẹ ọlọpaa fi si ọgba ẹwọn lati osu mẹta ṣẹyin.

Olumọ to ba BBC News Yoruba sọrọ ni inu awọn dun nitori awọn ọmọ mẹtẹẹta naa n ja fun ilẹ baba wọn ni.

O ni Iskilu Wakili to n ba ilu Ibarapa jẹ pẹlu ọpọlọpọ aṣẹmaṣẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC si fi ẹmi wọn lele ni wọn wa fi si ẹwọn fun oṣu mẹta.

Olumo ni: ''Ati ọlọpaa, soja, Amotẹkun ko si ẹni to ri Wakili mu, awọn ọmọ wọnyii ni wọn ja fitafita fun ilẹ Yoruba.''

''Lẹyin iṣẹlẹ yii ni awọn ọmọ Wakili ati awọn ọmọ Seriki Fulani Igangan pada lọ si ibẹ ti wọn si pa awọn eniyan, to si tun jo ile ọba Igangan pẹlu''.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Bi Iṣẹlẹ to gbe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta de ọgba ẹwọn ṣe ṣẹlẹ niyii...

Adari ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Ọyọ ni Ọjọ Keje, Osu Kẹta, ọdun 2021 ni iṣẹlẹ naa waye ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC fa Wakili le awọn agbofinro ọwọ ni Igbora.

''Ohun ti awọn ọlọpaa sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa ni wi pe ki wọn tẹle wọn lọ si olu ileeṣẹ wọn ni Eleyele, Ibadan lati bere ọrọ lọwọ wọn'

'Bi wọnm ṣe fi wọn si atimọle niyen pe eniyan kan ku lasiko rogbodiyan naa, ati wi pe ki wọn wa wi ti ẹnu wọn.'

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

'Amọ lẹyin naa wọn tu wọn silẹ ti wọn si gba oniduro wọn nitori ilera ara wọn.'

'Lẹyin ọṣẹ kan ni Kọmiṣọnna ọlọpaa pe ki awọn mẹtẹẹta yoju si wọn nitori wọn ni ibeere fun wọn, amọ lati igba naa ni wọn ti fi wọn si atimọle ni Kọmiṣọnna ọlọpaa si ni o ju agbara ohun lọ lati da wọn silẹ.'

Osu mẹta ni awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta naa lo ni ọgba ẹwọn nitori pe wọn mu Wakiti to n hu iwa buruku lagbegbe naa, ti awọn ọmọ rẹ si da ibọn bo wọn lasiko ti wọn lo koju rẹ ni Ibarapa.'

Oba

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Yoruba dalẹ̀ wa lórí àwọn ọmọ OPC mẹ́ta tí wọ́n tímólé láìṣẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Iskilu Wakili - Ẹgbẹ́ OPC

Ẹgbẹ OPC ni ohun to dun awọn julọ ni wi pe awọn lọbalọba kẹyin si awọn nigba ti awọn nilo wọn ju, paapaa awọn ọba Ibarapa mejeeje.

Oluomo ni awọn lọbalọba ni ilẹ Yoruba yẹ ki wọn ke sita lori awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn ti mọle naa nitori awọn ọmọ Yoruba ni wọn n ja fun.

O fikun wi pe awọn ọba yii ma nitori owo osu ti wọn gba lọwọ ijọba ki wọn wa dakẹ lai ṣe ohunkohun si ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ ni ilẹ Yoruba.

'O yẹ ki awọn ọba sọrọ soke pe iṣẹ ilu ni wọn ṣe, wọn da nkankan ṣe fun ara wọn'.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

'Amọ ki wọn ranti wi pe awọn to le jo aafin ọba Igangan le e ṣekọlu si ẹnikẹni ni ilẹ Yoruba lai wo ti ade ori wọn'

Bakan naa ni ẹgbẹ OPC fikun pe awọn mẹta ti wọn fi silẹ naa ti bẹrẹ si ni gba iwosan to tọ lati igba ti wọn ti gba ominira kuro ni ọgba ẹwọn naa.

OPC

Oríṣun àwòrán, Others

Iléẹjọ́ tí dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC tó mú Iskilu Wakili sílẹ̀ pé kí wọ́n máa lọ ní àlááfíà

Ileẹjọ Magisreti to wa nilu Ibadan nipinlẹ Oyo ti paṣẹ ki wọn tu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta to wa ni ikawọ ọlọpaa silẹ ni kiakia.

Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti mọle lori ẹsun wi pe wọn mu Wakili ti awọn ara Ibarapa ni ipinlẹ Ọyọ fi ẹsun ifipabanilopọ, ijinigbe ati ipaniyan kan.

Awọn mẹtẹẹta naa ti orukọ wọn n jẹ Dauda Kazeem, Awodele Adedigba ati Ramon Hasan ni awọn ọlọpaa ti mọlẹ ni Oṣu Kẹta ọdun yii lẹyin ti wọn tẹ Wakili.

Ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan wọn ni wi pe wọn da ina sun ile Wakili, ti ẹmi obinrin kan si lọ si iṣẹlẹ naa

Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC wọnyii ni wọn fa Wakili le ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lọwọ, ki ọlọpaa to ṣẹṣẹ wa ti wọn mọle ti wọn si gbe wọn lọ si ileẹjọ.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Lasiko ti iṣẹlẹ naa waye ni awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe wọn ti awọn to mu Wakili wa fun ọlọpaa mọle.

Amọ ileẹjọ ni Ọjọ Iṣẹgun paṣẹ wi pe ki wọn fi wọn silẹ, ki wọn ma a lọ ni alaafia, lẹyin ti ileejọ sọ wi pe ko si aridaju kankan lori ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta ọhun.

Ẹwẹ, lasiko ti wọn ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ohun mole ni Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams bu ẹnu atẹ lu bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ju awọn ọmọ ẹgbẹ OPC to wa labẹ rẹ si atimọle.

Gani Adams ni iranwọ lasan ni awọn OPC ṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa lori ati wa ojutu si eto abo to mẹhẹ kaakiri ipinlẹ Oyo.

Gani Adams ṣalaye ọdaran pọnbele ni Wakili, o ni o kan n dibọn lasan ni fawọn ọlọpaa.

Osu mẹta gbako ni awọn mẹtẹẹta lo ni atimole ki ileẹjọ to ṣẹṣẹ tu wọn silẹ lati ma a lọ ni alaafia nitori wọn ko jẹbi ẹsun kankan.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol