Honourable Olufunmi Rafiu Olatunji: Alága ìjọba ìbílẹ̀ Eti-Osa, Eko tí jádé láyé lẹ́yìn àìsàn

Oríṣun àwòrán, Others
Alaga ibilẹ Eti-Osa nipinlẹ Eko, Hon. Olufunmi Rafiu Olatunji ti jade laye.
Iroyinti wọn fi lede ni oju opo Facebook re fihan pe o ti ṣe diẹ ti aisan ti n ba finran ko to di wi pe o jade laye.
Ni ilana ẹsin Islam ni wọn yoo sin in ni ile rẹ to wa ni agbegbe Sngotẹdo, Ajah nipinlẹ Eko.
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- Ohun tó dára fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wá ni láti yá owó fún ṣíṣe ojú pópó wá - Fashola
- Gómìnà ṣàbẹ̀wò sí àwọn tí ọlọ́pàá yìnbon lù l'Enugu, Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìwádìí gbọdọ̀ wáyé kíákíá
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Ìgbẹ́jọ́ Kemisola Ogunniyi kò wáyé lóní, ó tún dọ̀la, ṣùgbọ́n... - Agbẹjọ́rọ̀
Ki o to salaisi, oun gbaradi fun idibo sipo alaga ijọba ibilẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ti yoo waye ni Ọjọ Kẹrinlelogun, Osu Keje, ọdun 2021 ni ipinlẹ Eko.
Oun lo gbegbe oroke ni idibo abẹlẹ pẹlu ibo 1977, ti yoo fi le gbe asia ẹgbẹ naa ninu idibo osu to n bọ ọhun.
Awọn oṣiṣẹ oniroyin alaga naa to fi lede loju opo ikansiraẹni Facebook rẹ ni ''pẹlu ibanujẹ ọkan ni awọn fi n kede iku ọga awọn awọn lẹyin aisan ọlọjọ gbọọrọ''
''Alẹ Ọjọ Ajẹ, Ọjọ Kọkanlelogun, Osu Kẹfa, ọdun 2021 ni o jade laye ni wọn yoo sin si ile rẹ.''
Lara awọn to ba a kẹdun lori Facebook naa ṣepajuwe rẹ gẹgẹ bi eniyan nla to ni aanu awọn eniyan.
- Ṣé lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ogun òfurufú Nàìjíríà ṣèèṣì pa máàlú 1,000 ní Nasarawa?
- Ẹ wo bí olówó 'billionaire', Usifo Ataga ṣe kú ikú òjijì ní Eko
- Ajínigbe sún gbàgbé láwọn 15 nínú àwọn 156 tí wọ́n jí gbé ní Tegina bá sálọ
- Wo ǹkan méje tí o lè má mọ̀ nípa Fola Alade to ya ilé '1004 Estate' tó dolóògbé
- Wo ìdí tí EFCC fi fẹ́ wádìí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun láti ọdun 2015 dí àsìkò yìí














