Ìjàmbá ṣé ajínigbe tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 156 gbé ní ìpínlẹ̀ Niger, èèyàn 15 ṣílẹkùn sá mọ́ wọ́n lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, AFP
Iroyin ayọ leleyi lati ipinlẹ Niger nibi ti eeyan mẹẹdogun kan ti ribi sa mọ awọn ajinigbe lọwọ.
Awọn to ribi bọ yi wa lara awọn eeyan ti wọn ji gbe papọ mọ awọn akẹkọọ mẹrindinlọgọjọ ni ile ẹkọ Salihu Tanko loṣu kaarun ọdun yi ni Tegina.
Iroyin ta ri ka ninu iwe iroyin Naijiria Daily Trust sọ pe lasiko tawọn ajinigbe yi sun lọ lawọn eeyan wọn yi rapala jade ninu ile ti wọn gbe wọn pamọ si ninu igbo.
Ki wọn baa ma ri wọn mu, niṣe ni wọn gba ọna ọtọọta sa lọ.
Ọkan lara awọn to kọkọ pada de Tegina lo ṣalaye bio wọn ṣe moribọ fun awọn araalu.
Lẹyin igba naa ni ijọba ipinlẹ Niger wa gbe igbesẹ lati ṣe itọju ati iranlọwọ fawọn to ribi jajabọ yi.
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa bí agbébọn ṣe gbẹ̀mí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Titus Badejo Ejanla ní ìlú Ibadan
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
- Ẹ wo bí olówó 'billionaire', Usifo Ataga ṣe kú ikú òjijì ní Eko
A gbọ pe ẹni yi wa ni ile iwosan nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Iroyin taa tun gbọ fi kun pe awọn mẹta miran to jajabọ wọ inu ilu Tegina lafẹmọju ọjọ Aiku ti ọkan lara wọn si n gba itọju lọwọ ni ilu Minna.
A ko ribi fidi rẹ mulẹ ṣugbọn wọn ni awọn mii to jajabọ ti wa ni Zaria.
Ohun taa gbọ ni pe igbo kijikiji kan ni Zamfara ni wọn gbe awọn akẹkọọ ati awọn mii salọ si lẹyin ti wọn ji wọn gbe kuro ni Tegina.
Ṣaaju ni Gomina Niger ti kede pe awọn ribi doola ọmọ ile keu mọkanla ninu awọn ti wọn ji gbe yi.
Lati igba naa, wọn ko ti ribi doola ẹnikankan mọ titi di oni.












