Tope Alabi and Yinka Alaseyori: Tope Alabi ti padà sọ̀rọ̀ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro mi

Oríṣun àwòrán, Instagram/adeyinka alaseyori/tope alabi
"Imoore si gbogbo eniyan"
Gbajugbaja olorin ẹmi, Tope Alabi ti pada sọrọ lẹyin ọsẹ kan ti ẹnu ti n kun-un nitori ọrọ kan to sọ lori orin Oniduro mi.
Ọjọ Satide to kọja ni iroyin kọkọ ti n ru eefin, lẹyin ti fidio kan jade sori ayelujara nibi ti Tope ti n sọrọ pe orin Oniduro mi ti akẹẹgbẹ rẹ, Adeyinka Alaṣeyọri kọ, ko ba ilana ati itọni Ẹmi Mimọ mu.
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àláfíà jọba lórí orin "Oniduro Mi", ìyá ni Tope Alabi jẹ́ sí mi - Adeyinka Alaṣeyori
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Wòlíì Genesis fèsì lórí ọ̀rọ̀ Tope Alabi nípa orin 'Oniduromi'
- O kú ogun àjàyé Tope Alabi, odò Jodani lo ṣẹ̀ṣẹ̀ là kọjà yìí o! Àmọ́ rántí pé ... - Mike Bamiloye
Nibi iṣẹ kan ti Tope ti lọ kọrin lo ti sọ ọrọ naa lori itage pe "Ọlọrun tobi ju nkan to le jẹ Oniduro ẹnikẹni".
Lati igba naa si ni awọn ọmọ Naijiria nile ati lẹyin odi ti n gba ọrọ naa bi ẹni gba igba ọti.
Bi ọpọlọpọ ninu wọn ṣe n sọ oko eebu ati ọrọ ibawi si Tope Alabi, ni awọn kan n ṣatilẹyin fun pe eniyan ẹlẹran ara ni.
Koda, lasiko ti laasigbo naa n gbona girigiri ni ẹlomii, Arabinrin Tolu Adelegan naa ba jade sita pe oun gan-an ni oun ni orin Oniduro.
Bi ọrọ naa ṣe gbona to fun bi ọjọ marun-un lẹyin ti fidio naa jade, Tope Alabi ko sọrọ nipa rẹ ni gbangba.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Koda, ko ba oniroyin kankan sọrọ, nitori pe ọpọ igba ni BBC Yoruba naa gbiyanju lati ba a sọrọ, amọ to ja si pabo.
Ṣugbọn nigba to di ọjọ Ẹti, ni iroyin kan ba tun jade sita pe Tope Alabi ti tọrọ aforiji lọwọ Adeyinka Alaṣeyọri .
Ṣe lootọ ni, tabi irọ?
Titi di asiko ti a n ko iroyin jọ, a ko le sọ pato ibi to jẹ orisun titọrọ aforiji naa rara. Idi ni pe Tope Alabi ko ba oniroyin sọrọ, bẹẹ ni ko kọ ohunkohun si oju opo ayelujara rẹ.
Amọ nkan to tun jẹ arigbamu ni nkan ti ogbontagi oṣere Kristiẹni, Mike Bamiloye sọ ninu atẹjade kan to fi gba awọn akọrin ẹmi naa ni imọran.
Ninu ọrọ to kọ si ori Facebook, Bamiloye sọ pe oun dupẹ Tope Alabi pe o ṣe ohun to tọ pẹlu awọn aforiji to fi sita o si gbadura fun un pe Eṣu yoo maa ri itiju lori aye rẹ titi lae ni.
Ṣugbọn lara awọn nkan ti a ri ninu atẹjade naa to wa lori ayelujara, ati iroyin abẹle ni pe o ni oun gba pe aṣiṣe ni bi oun ṣe sọ ọrọ to yẹ ko wa ni ọkan oun ni gbangba laarin ọpọ ero.
Ati pe ọmọ agbo-ile igbagbọ jọ ni oun, Alaṣeyọri ati Tolu Adelegan to ni orin gan-an.
Bakan naa ni iroyin sọ pe o ni ọmọ ninu igbagbọ ni Alaṣeyọri jẹ fun oun, ti oun si ni ifẹ rẹ pupọ, debi pe oun n gbadura fun aṣeyọri rẹ.
Tope Alabi dupẹ lọwọ gbogbo eeyan
Ẹni ti a ṣe loore ti ko dupẹ, Bibeli sọ pe o da bi ọlọṣa to ko ni ni ẹru lọ.
Ninu atẹjade to fi sita ni oru oni, ọjọ Aiku, ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, Tope Alabi sọ pe oun dupẹ lọwọ gbogbo eniyan fun aduroti wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ko sọ ni taara nipa nkan ti aduroti naa tumọ si, tabi mẹnu ba ọrọ orin Ondiro mi, o ni oun n fi ẹmi imoore han si gbogbo eniyan.
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
- Timothy Obadare ìránṣẹ́ Ọlọ́run to fọ́ lójú ìta ṣùgbọ́n tó ríran jù ọ́pọ́ wòlíì lọ
- Sunday Igboho ní December lòpin ìrìn àrè, Yorùbá ń lọ kúrò ní Nàíjíríà
- Ìjọba, ẹ bá mi wá ẹni tó pa ọmọ mi jáde - Ẹ̀bí olóògbé gbarata
- Mo kú tì, nítorí pé àsìkò mi kòì tó láti padà sí ọ̀run- Kunle Ologundudu
Awọn koko nkan to sọ
Awọn to gbala ni idunnu rẹ,
Jesu yoo di wa mu ṣinṣin,
Iyebiye ni wiwa ni ibi mimọ rẹ,
Yoo di wa mu ṣinṣin,
Ko ni i jẹ ki ọkan wa ki o sọnu,
Ileri rẹ yoo duro titi,
Ti a ra nipa rẹ ni owo iyebiye,
Yoo di ẹni kọọkan wa mu ṣinṣin.
O ṣaasọ pe oun dupẹ pupọ lọwọ gbogbo awọn to duro ti oun lati bi ọsẹ kan, "Ọlọrun ko ni fi gbogbo wa silẹ ni orukọ Jesu.
"Ẹ ṣeun pupọ, ki Ọlọrun ko bukun fun yin ni orukọ Jesu.
"Amin.
"Mo nifẹ gbogbo yin."



















