Adeyinka Alaseyori and Tope Alabi: Wòlìí Genesis ní òun ni orin Oniduro Mi wà fún

Oríṣun àwòrán, other
Oluṣọ aguntan agba fun ijọ Celestial Church of Christ, Genesis Global, Ẹniọwọ Israel Ogundipe ti sọ pe ohun ti gbajumọ akọrin ẹmi, Tọpẹ Alabi sọ lori orin Oniduromi ku diẹ kaa to.
Ẹniọwọ Ogundipẹ ṣalaye ninu fido kan to n lọ kaakiri bayii ninu eyi to ti n kọ orin "oniduromi ẹ ṣeun" pe oun gan ni orin naa wa fun, bi awọn eeyan ko ba mọ.
"Oniduro mi ni alagbawi mi. O duro fun mi nigba ti ọpọ fi mi silẹ lori ẹjọ ti mo ko si, ti ọpọlọpọ si tun rin jinna si mi nitori pe wọn ko fẹ ki aye mọ wọn mọ mi."
- Ìròyìn Yàjóyàjó -'Yinka Alaseyori fèsì sí Tope Alabi fún ìgbà àkọkọ lẹyìn wàhálà orin “Oniduro Mi”, wo ohun tó sọ
- Ìjọ Islam fìwé pe Wòlíì Genesis bíi àlejò pàtàkì sí òru Lailatul Quadir, ariwo sọ
- Àwọn ìwàásù akọnilẹ́nu hàà tí Prophet Israel Oladele CCC Genesis Global ti ṣe rèé
- Genesis Global: Sáká lara Woli Israel Ogundipe dá, kìí ṣe àìlera ló mú kí wọn fi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n
- Wòlíì míì, tún wọ gàù lẹ́yìn tó tàpá sí ìlànà béèlì tí wọ́n fún un nílé ẹjọ́
Oluṣọ aguntan ijọ Genesis Global naa wa fi kun un pe, o dara ki Ọlọrun jẹ Oniduro ẹda dipo eniyan ẹlẹran ara.
"Emi ni olorin ẹmi naa kọ orin naa fun. Koda nigba ti awọn ile ẹjọ da iṣẹ silẹ, Ọlọrun duro fun mi."
Laipẹ yii ni awuyewuye hu sita lori ọrọ ti Tọpẹ Alabi sọ ninu fidio kan to ja ranyinranyin kaakiri.
Tope Alabi ni akude wa lori orin naa ati pe ko jẹ jẹ latọwọ Ẹmi mimọ lo ti wa nitori pe Ọlọrun sọ fun oun pe oun kọja Oniduro fun ẹnikẹni.
- Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti
- Jàǹdùkú ti já ọdún eégún gbà n‘Ibadan, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti sùn - Ẹgbẹ́ ọlọ́dẹ pariwo
- Iyabo Ojo tún sọ òkò ọ̀rọ̀ sáwọn òṣèré tíátà nínú fídíò tuntun tó gbé síta
- Ìjọba Oyo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn oníbárà kúrò láàrin ìgboro ìlú Ibadan
- Fífẹ́ ọkùnrin ẹgbẹ́ mi jẹ́ ìgbésẹ̀ tó burú ju tí mo gbé láyé
- A ó sọ ibùdókọ̀ ojú irin ìlú Ibadan di gbàgede káràkátà láìpẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
- Wo iye owó tí ìjọba Naijiria ti yá lọ́wọ́ China láti ìgbà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gorí àléfà
Lati igba to si ti sọrọ naa, eyi to gba ori ayelujara, ni oniruuru eeyan ti n fesi nipa rẹ, eyi ti ko yọ awọ̀\n gbajumọ awujọ silẹ.


















