Prophet Shepherd Bushiri: Iléẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé ilé wòlíì tí iye rẹ̀ tó $350,000

Shepherd Bushiri

Oríṣun àwòrán, @TanzaniaUpdates

Adajọ ti pasẹ ki wọn gbẹsẹ le ile wolii Shepherd Bushiri lẹyin to tapa si ilana beeli rẹ ti wọn fun un.

Awọn oniroyin ni iye owo ile naa to wa ni Pretoria to $350,000.

Adajọ yi ti saaju ni ki wọn ko iwe ile yi kalẹ fun ile ẹjọ lori ẹsun gbajuẹ ti wọn fi kan wolii ọhun ati iyawo rẹ nilẹ South Africa.

Bayi ti wọn kọ lati tẹle ilana beeli ti wọn gba lọwọ ile ẹjọ, adajọ ti ni ki wọn gbẹsẹ le ile wọn yii.

Ọrọ yi waye lẹyin ti Bushir na papa bora pada lọ si orileede rẹ Malawi .

Ẹwẹ, ile ẹjọ kan ni Malawi ti wọn salọ ti tu awọn mejeji silẹ lẹyin ti wọn saaju gbe wọn wa siwaju rẹ lonii.

Shepherd Bushiri

Oríṣun àwòrán, @namibiansun

Amọ sa, awọn alasẹ ni South Africa si n tẹnu mọ pe Bushiri ati iyawo rẹ gbọdọ wa wi tẹnu wọn lori ẹsun gbajuẹ ti wọn fi kan awọn mejeeji nibẹ.

Wolii Bushiri ati iyawo rẹ ko sinmi lati sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn, ati pe nitori ewu ti ẹmi awọn wa lo jẹ kawọn na papa bora lọ si Malawi.

Nibayi, South Africa ti fi iwe asẹ sita pe ki awọn alasẹ Malawi da wọn pada lati wa foju wina ofin.

Wolii Bushiri jẹ ilumọọka oniwaasu ọmọ Malawi to n dari awọn ile ijọsin ni Ghana ati South Africa.

Àkọlé fídíò, Tí mo ba ti múra bí ọkùnrin fi kọrin, kò sí ọ̀dọ̀ ààrẹ́ tí mi ò lè wọ̀- Erelu, ọmọ Elemure Ekiti

Bushiri ni oludasilẹ Evangelical Church Gathering ni South Africa to si pẹka de awọn ilẹ Africa mii.

Wolii yi ti figba kan sọ pe oun da ara awọn eeyan ya lọwọ arun AIDS, oun le sọ afọju dẹni to n ri iran kedere, oun le sọ talaka di olowo, koda o ni oun le fẹsẹ rin lori ofurufu.

Shepherd Bushiri

Oríṣun àwòrán, @CapitalFMMw

Bushiri ti sọ fun oloselu Zimbabwe kan, Kembo Mohadi pe wọn yoo de lade saaju ki o to pada wa di igbakeji aarẹ ilẹ naa gẹgẹ bi iwe iroyin New Zimbabwe se

Fọfọ ni papa isere maa n kun nigbakigba to ba se akojọ iwaasu nibẹ.

Ọpọ si ti ni o wa lara awọn pasitọ to lowo julọ nilẹ Africa.

Ọrọ Bushiri ati iyawo rẹ di ohun tawọn eeyann ran lẹnu lẹyin ti oun ati iyawo rẹ sa mọ ile ẹjọ lọwọ lọ si Malawi lẹyin ti wọn gba beeli wọn.

Shepherd Bushiri

Oríṣun àwòrán, @DumaFMRadio

Esun magomago ati iwa jibiti ni wọn fi kan wọn.

Awọn ọlọtẹlẹmuyẹ sọ pe, ẹjọ naa nii se pẹlu jibiti owo to to miliọnu mejilelọgọrun owo South Africa.

Saaju lo ti kọkọ yọju nile ẹjọ Majistireeti Pretoria lori ẹsun yi lọjọ kọkanlelogun osu Kẹwaa, ti adajọ si gba beeli rẹ lọjọ Kẹrin, osu Kọkanla.sọ.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?