Donald Trump: Àkọbí ọmọ ààrẹ, Donald Trump Jr ti lùgbàdì Covid-19

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Akọbi ọmọ ọkunrin aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump naa ti lugbadi aarun Coronavirus gẹgẹ bi agbẹnusọ rẹ ṣe fi sita.

Donald Trump Jr to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji lọ ṣe ayẹwo lọsẹ yii, nigba to gba esi, o ti wa ni iyasọtọ ninu ile rẹ lati igba naa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ fi sita, o ni ko si ifarahan awọn ami teeyan le fi mọ pe o ni aarun ọhun bẹẹ si ni o n tẹle gbogbo ofin Covid-19.

Don Jr ni ọmọ Trump ẹlẹẹkeji ti esi Covid-19 rẹ yoo jẹ bẹẹni.

Àkọlé fídíò, Tí mo ba ti múra bí ọkùnrin fi kọrin, kò sí ọ̀dọ̀ ààrẹ́ tí mi ò lè wọ̀- Erelu, ọmọ Elemure Ekiti

Baron Trump to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla ti kọkọ lugbadi rẹ loṣu to kọja ṣugbọn ara tirẹ tete ya.

Donald Trump Jr jẹ akọṣẹmọṣẹ ninu sisọrọ nita niwaju araalu to jẹ pe o ko ipa pataki ninu ipolongo idibo baba rẹ.

Ọgbẹni Trump funra rẹ naa gba esi ayẹwo pe o ni Coronavirus nibẹrẹ oṣu kẹwa to si lo ọjọ mẹta nileewosan. Bakan naa ni iyawo rẹ, Melania Trump gaan ko aarun ọhun.

Oṣu to kọja ni wọn fi ẹsun kan Don Jr toripe o sọ ootọ nipa awọn eeyan to ti ku latari Covid-19 l'Amẹrika.

Arun naa ti ran awọn to din diẹ ni miliọnu mejila (11.8 million) ti awọn to din diẹ lẹgbẹrun lọna ọtalenigba (253,000) si ti gba ibẹ ku.

Donald Trump Jr

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wo àwọn tó kàgbákò Covid-19 ní White House lẹ́yin Ààrẹ Trump

Awọn ara ile Trump

Aarun Covid-19 tubọ n pọ sii ni ile ijọba orilẹede Amẹrika, paapa laarin awọn to sunmọ Aarẹ Donald Trump.

Lẹyin ti Trump ati aya rẹ, Melania, ni aarun naa l'ọsẹ to kọja, oludamọran fun ile ijọba, Stephen Miller, ati ọga ologun kan, ti ni i.

Ọjọ Iṣẹgun ni Miller kede sita pe oun ti ni coronavirus.

Bakan naa ni ọpọlọpọ awọn ọga ologun ti wa ni iyasọtọ nitori aarun naa, lẹyin ti ọkan lara wọn, Charles Ray ni i.

Ọjọ Iṣẹgun ni oludamọran fun Trump, Stephen Miller sọ pe oun ni coronavirus

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọjọ Iṣẹgun ni oludamọran fun Trump, Stephen Miller sọ pe oun ni coronavirus

Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Trump ti pada sile ijọba, alatako rẹ to tun jẹ oludije fun ipo aarẹ ninu eto idibo to n bọ lati inu ẹgbẹ oṣelu Democrat, Joe Biden, ti sọ pe Trump ko gbọdọ ba oun ṣe itakusọrọ ti aarun naa ko ba tii fi silẹ.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹwaa ni awọn mejeeji yoo tun fojurinju ni Miami, Florida.

Oun ti a mọ nipa bi Miller ṣe ko coronavirus

Oludamọran Aarẹ Trump ọhun sọ pe oun ti wa ni iyasọtọ lati ọjọ Iṣẹgun to ti mọ pe aarun naa ti wọ lara.

Iyawo rẹ, Katie Miller, to tun jẹ agbẹnusọ fun Igbakeji aarẹ Mike Pence, ko Covid-19 l'oṣu Karun-un, amọ o pada ri iwosan.

Àkọlé fídíò, Njẹ Chloroquine nipa kankan lati le koju Coronavirus

Ninu oṣu Keje, Iya agba Miller, to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọrun, Ruth Glosser, kú nitori ilera rẹ ti Covid-19 bajẹ.

Ile ijọba 'White House' sọ pe o fọwọ rọri ku ni gẹgẹ bi arugbo, pe kii ṣe coronavirus lo pa.

Ṣugbọn, ibatan Miller kan, fi iwe ẹri iku iya agba naa sita, ninu eyi ti wọn kọ ọ si pe aile mi daada, ati pe Covid-19 "jẹ pataki" ninu nkan to fa iku Arabinrin Glosser.

Ọgbẹni Miller lo ma n kọ awọn ọrọ apilẹkọ ti Trump ma n sọ ni gbangba - o si jẹ gbajugbaja fun ọwọ lile to fi mu ọrọ bi awọn atipo ṣe n wọ ilẹ amẹrika.

Yatọ si awọn wọnyi, amugbalẹgbẹ iyawo Trump, Hope Hicks, ati awọn sẹnetọ ẹgbẹ oṣelu Republican, naa ti ni aarun ọhun.

Àkọlé fídíò, Ìdájọ́ òdòdò ló fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Sotitobire - Agbẹjọ́rò fún ìjọba

Ààrẹ ilẹ̀ Amẹríkà, Donald Trump tún yẹrẹpẹ ààrùn Coronavirus bó ṣe n kúrò nílé ìwòsàn

Bí ìgbà tí ènìyàn ń ṣe eré orí ìtàgé ni ààrẹ Donald Trump ń fi ọ̀rọ̀ coronavirus ṣe gẹgẹ bi yóò ṣe padà si ilé ijọba lónìí, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta nílé ìwòsàn.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé ààrẹ Trump sì lè kó ààrùn náà ran àwọn tó wà ni àyíkà rẹ̀, síbẹ̀ ó yọ ìbòmú rẹ̀ lórí fàrándà tí o dúró sí nilé ìjọba.

Oníṣegùn rẹ ni àwọn yóò ṣì maa fún un ni ìtọ́jú láti ilé ìjọba, nítorí ararẹ̀ kò tíì dá tán.

Ọ̀pọ̀ àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Trump ló ti ni ààrun náà láti bi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn.

Ṣùgbọ́n, ìbéèrè tó wà lẹ́nu ọ̀pọ̀ ènìyàn ni pé ṣe lóòtọ́ ni ààrẹ Donald Trump ṣe àìsàn.

US President Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ṣáájú lẹ́yìn tí ààrẹ ń lọ sí ilé ìwòsàn lọ́ja Ajé ló kéde pé kí àwọn ènìyàn má bẹ̀ru ààrùn náà rárá, ''ẹ má ṣe jẹ́ ki ìbẹ̀rù rẹ̀ gba àkóso ayé yín.

Trump nínú àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ̀ "Ara mí yá gágá jú tí ogún ọdún sẹ́yìn lọ"

Bákan náà ló sọ pé " òun kò ni pẹ́ pada fún ìpolongo ìdìbò"

Donald Trump: Ó lé ọjọ́ méjì tí Ààrẹ ilẹ́ Amerika ń lò ní ilé ìwòsàn

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Twitter/Donald Trump

Aarẹ orilẹede Amerika, Donlad Trump to ti lo ọjọ keji ni ile iwosan lẹyin to lugbadi arun Coronavirus, ti dupe lọwọ awọn ololufẹ rẹ, to si sọ wi pe oun wa ni alaafia.

Oju ọpọ ikansiraẹni Twitter rẹ ni aarẹ naa fi idupẹ ohun si, lẹyin ti awọn ololufẹ rẹ ṣewọde pẹlu asia ''Make Americas Great Again'' ni iwaju ileewosan Walter Reed Medical Center nibi ti aarẹ naa ti n gba iwosan.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Awọn dokita rẹ sọ wipe ara Trump n dahun si itọju ti wọn n fun un, amọ Adari Ile Ijọba, White House sọ wi pe o ṣeeṣẹ ki ilera rẹ buru jai si.

Dokita Aarẹ Trump ni aṣiṣọ ọrọ ni wi pe aarẹ Trump ti ni aarun Coronavirus ki o to di wi pe o yọju si ileewosan.

Iyawo aarẹ orilẹede Amerika, Melania Trump wa lara awọn eniyan ti wọn sunmọ aarẹ Trump to ti lugbadi arun naa, amọ oun gba itọju ni ile ijọba.

Nibayii, eniyan meje to wa nibi ayẹyẹ to waye ni White House ni ọsẹ to kọja lo ti lugbadi arun naa.

Trump to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin ni awọn eniyan ti bu ẹnu atẹ lu wi pe o fi oju tẹmbẹlu arun naa, lai wọ ibomu tabi ofin iyagofunraẹni lo ṣe lugbadi arun naa.

Donald Trump ṣe dèrò ilé ìwòsàn torí àrùn Coronavirus tó mú u

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ni wsn ti gbe lọ sile iwosan ologun fun itọju lẹyin to lugbadi arun Coronavirus.

Ọjọ Ẹti ni ariwo ta yika agbaye pe aarẹ ilẹ Amẹrika ati aya rẹ naa ni kokoro arun shun n ba finra.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nigba to n sọrọ lori ipo ti ilera Trump wa, Dokita rẹ, Sean Conley ni o rẹ aarẹ naa diẹ amọ ọkan rẹ wa nipo to dara, ti oun gan si n se daradara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn ti gun Trump ni abẹrẹ ati oogun Remdesivir, lati wo kokoro arun naa san lara rẹ.

Àkọlé fídíò, Yomi Fabiyi: Fíìmù ‘Owó orí ẹlẹ́wọ̀n’ jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà ìpọ́njú làá mọ ọ̀rẹ́

Trump ti fi igi gun eto ipolongo ibo rẹ nibayii ti eto idibo aarẹ Amẹrika, ninu eyi to ti n kopa ku osu kan soso pere.

Ile ijọba ti wa kede pe, Trump yoo wa nile iwosan fun ọjọ diẹ nitori lara apẹẹrẹ tawọn n ri lara rẹ ni pe o ni iba.

Wo ìgbà méje tí Donald Trump ti yẹpẹre àrùn Coronavirus

Donald Trump ati aya rẹ, Melania

Lati nnkan bi oṣù mẹwaa sẹyin ni ọpọ awọn ọmọ ilẹ Amẹrika kigbe pe ọwọ ti aarẹ Donald Trump fi mu aarun Coronavirus ko bojumu tó ati pe ni ọpọ igba lo ma a n ṣe bii pe arun ọhun kii ṣe ootọ.

Awọn eniyan ilẹ Amẹrika, ni Trump maa n mu ootọ diẹ ati irọ diẹ papọ, to ba n sọrọ lori Covid19.

Idi ree ti BBC fi se akojọpọ awọn ọrọ to safihan bi Donald Trump ṣefi ọwọ yẹpẹrẹ mu Coronavirus:

Awọn igba ti Donald Trump ti sọrọ Coronavirus bii nnkan yẹpẹrẹ:

  • Lati igba ti aarun Coronavirus tí bẹrẹ naa ni aarẹ Donald Trump ti n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu
  • New York wa ninu isoro, sugbọn mo ń igbagbọ pe wọn yoo jajabọ.
  • Ninu oṣu kẹrin Trump ni lootọ ni ajọ to n mojuto ajakalẹ arun sọ pe eniyan maa lo ibomu gẹgẹ bí ọna lati dẹkun aarun naa
  • Ni ọjọ kẹfà osu keje aarẹ Trump sọ pe iku to n waye lori "China virus" bi o se maa n pe, ko ju ida mọkandinlogoji lọ.
  • " Ko si orilẹ-ede to n sayẹwo to wa, koda, o n ṣiṣẹ fun wa gan ni, a n ṣe ayẹwo, a si n ri awọn ẹgbẹgbẹrun eniyan to ni aarun naa
  • Ni ọjọ kejila oṣu kẹsan Trump ni, abẹrẹ ajẹsara Coronavirus ko ni pẹ yanju sugbọn bo de bi ko de, a o bori rẹ
  • Ayẹwo Coronavirus ti a n se ju milọnu mẹẹdọgbọn lọ, eyi sì ni o mu ki wọn maa ri wa bí pe, arun yii pọju lọdọ wa ju awọn orileede miran lọ.

Diẹ ree ninu ọrọ aarẹ Donald Trump ti awọn eniyan fi sọ pe, o fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ Coronavirus, ti oun gan-an fi wa lugbadi aarun naa bayii.

Trump, ọwọ́ ara ààrẹ ló fi pe Coronavirus fún ara rẹ̀ - Aráàlú

Donald Trump

Lowurọ ọjọ Ẹti ni iroyin tan ka gbogbo agbaye pe aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti lugbadi aarun Coronavirus.

Ọrọ naa lu sita lẹyin ti Trump fi atẹjiṣẹ sori twitter rẹ pe, oun ati iyawo oun ti lugbadi aarun Coronavirus.

Bakan naa lo fi kun pe, awọn ti gbe igbesẹ lati ya ara awọn sọtọ, ti awọn yóò si ri iwosan gba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kini awọn ọmọ ilẹ Amẹrika n sọ?

Ọpọ awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lo dabi ẹni pe ikede aisan Trump yii jẹ iroyin ayọ fun wọn, bo tilẹ jẹ pe, ko dun mọ awọn kọọkan ninu.

Ọpọ si lo n yọ Trump pe ọwọ ara rẹ lo fi fa arun naa funra rẹ, nitori ọwọ yẹpẹrẹ to fi mu lati ilẹ wa.

Donald Trump ati aya rẹ, Melania

Oríṣun àwòrán, @ASK_des

Ọkan lara awọn to fesi si ọrọ Trump sọ pe, "o dara bẹẹ, iwọ lo faa

Iwọ nikan ṣoṣo lo yẹ ko daa duro, o yẹ ki o doola ọpọ ẹmi.

O wa n fẹ ki awọn eniyan maa kaanu rẹ nisin yii."

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ẹlomiran tilẹ ni, aarun naa ti kuro ni 'China virus ' o ti di 'Trump Virus'

Rhoma McGuire ni tirẹ ni, oun ko ni igbagbọ pe lootọ ni Trump ni aarun naa nitori opurọ ni.

"mi o le gba ohunkohun to ba ti ẹnu rẹ jade gbọ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Swilson ni oun ko kaanu kankan fún Trump, bo ba tilẹ ni aarun naa nitori pe iya oun wa nile iwosan níbi ti o ti n ja fun ẹmi ẹ.

Eyi ṣẹlẹ nitori Trump kọ lati ṣe iṣẹ rẹ botitọ ati boti yẹ, mo si gba pe ẹsan 'karma' n ṣiṣẹ lootọ. "

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Awọn miran ni sebi Trump yii kan naa lo maa n fi Joe Bidden ṣe yẹyẹ nitori pe o n lo ibomu, ọrọ naa ti kan oun naa bayii.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Koda awọn kan rọ Trump pe ko maa lọ mu 'bleech' o, gẹgẹ bo se gba awọn eeyan to ni arun Coronavirus niyanju.

Ta ba wo awọn esi ti ara ilu fun Trump lori ikede arun Coronavirus to ni, eyi fi han pe igbesẹ tí aarẹ gbe lasiko ti ajakalẹ arun naa bẹ silẹ nilẹ Amẹrika ,ko koju osuwọn to.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Donald Trump àti ìyàwó rẹ́ ti lùgbàdì àrùn CoronaVirus

Aworan aarẹ Trump ati Iyawo rẹ Melania

Oríṣun àwòrán, Reuters

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe aarẹ orileede Amẹrika Donald Trump ati iyawo rẹ Melania Trump ti lugbadi Covid-19.

Awọn mejeeji wa ni iyasọtọ .

Loju opo Twitter rẹ aarẹ funrarẹ kede ọrọ naa .

Iṣẹlẹ yi n waye lẹyin ti ọkan lara awọn to jẹ wọlewọde aarẹ Trump Hope Hicks lugbadi arun naa.

Hicks ẹni ọdun mọkanlelọgbọn jijọ ba aarẹ Trump rin ninu ọkọ baalu rẹ Air Force One lọ si Ohio nibi ti itakurọsọ laarin Trump ati Biden ti waye.

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 7

Dokita aarẹ Trump Sean Conley fi ọrọ sita pe alaafia ni aarẹ ati iyawo rẹ wa ti wọn si gbero lati duro si ile ijọba lasiko iyasọtọ wọn

Loju opo Twitter awọn eeyan ti n fesi si iṣẹlẹ yi.

Bawọn kan ti ṣe n ba aarẹ Trump daro lawọn miran n sọrọ kobakungbe si.

Skip X post, 8
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 8

Skip X post, 9

End of X post, 9

Skip X post, 10

End of X post, 10

Ko ti daju iye ọjọ ti aarẹ yoo fi wa ni iyasọtọ ṣugbọn idibo aarẹ Amẹrika ku oṣu kan bayi.

Aarẹ Trump jẹ ẹni ti ko ka ọrọ Covid-19 si ti o si tun fi alatako rẹ Biden ṣe yẹyẹ pe o wọ ibomu lasiko itakurọsọ to waye laipẹ yi.

Ṣaaju asiko lo ti sọ orisirisi ọrọ eyi to tako ohun tawọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun sọ nipa aarun naa.