EFCC arrests 10 in Oyo: Àwọn afurasí mẹ́wàá ní EFCC mú ní Ibadan lórí ẹ̀sùn gbájúẹ̀

awọn ọdọ ti wọn mu naa

Oríṣun àwòrán, Efcc

Àjọ EFCC ti mú ọdọkùnrin mẹwàá lórí ẹsùn jìbìtì lílù lórí ayélujára ní Oyo

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria ti a mọ si Economic an Finanicial Crimes Commisssion, EFCC ti mu awọn ọdọ mẹwaa lori ẹsun jibiti ori ayelujara ni Ibadan.

Awọn ti ọwọ tẹ naa ni: Isaac Ogundayo, Abass Sodiq, David Ayodele, Kelvin Etiowe, Afolabi Seun, Saheed Olalekan, Oluwatobi Damilola, Sukanmi Odofin, Ademola Okumola, ati Joseph Damilare.

Ogbeni Wilson Uwujaren to jẹ adari ẹka ifitonileti fun ajọ EFCC ni ipinle Oyo salaye pe ibuba wọn ni ojule 4, Opopona Ajinde, ni Akala Expressway ni Ibadan.

O ni laarọ oni ọja Eti ni EFCC lọ ka wọn mọ lẹyin ti wọn ti gba ifitonileti lati ọdọ awọn eeyan kan ni ọpọlọpọ ọsẹ sẹyin.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Uwujaren ni wọn yoo gbe awọn mẹwẹẹwa yoo foju a ile ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori wọn,

O salaye pe iwadii naa ni yoo sọ́ iru ẹ́sun ti wsn yoo fi koju koowa ninu wọn

Àkọlé fídíò, Ìṣẹ̀lẹ̀ Kàyéèfì: Ìpáǹle tú Abass Owonikoko sí ìhòòhò ayé, kó tó gba kéú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n