Egypt Air: Inú wa dùn pé Hiyam Nasr Daaban tó jẹ́ Ìyá àti ọmọ wà ní àlááfíà

Oríṣun àwòrán, Egypt air
Ọkọ̀ ọ̀fẹ́ ní ọmọ tuntun jòjòlò tí wọ́n bí sínú ọkọ̀ òfurufú yóò máa wọ̀ títí ayé rẹ̀- Egypt Air
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Arabinrin Hiyam Nasr Daaban lo dede bẹrẹ si ni rọọbi ninu ọkọ ofurufu Egypt Air , eleyii to mu ki awakọ ofurufu naa tiraka lati ba silẹ ni pajawiri.
Ọpẹlọpẹ dokita to wa ni ọkọ baalu naa lo gbẹbi arabinrin naa, ti o si bi ọmọ naa ni ayọ ati alaafia.
Awọn alasẹ Egypt Air fi idunnu wọn han pupọ.
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye
- Àwọn ọlọ́ṣà sùn lọ nínú ọkọ̀ tí wọ́n jí, lọ́wọ́ agbófinró bá tẹ̀ wọ́n
- Wo ìgbà méje tí Donald Trump ti yẹpẹre àrùn Coronavirus
- Àyọ́jọ́ ọjọ́ Òmìnira Nàìjíríà: Sanwo-Olu gbàlejò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ̣ogọ́ta, El-Rufai dá ẹlẹ́wọ̀n 25 sílẹ̀
- Àjọ EFCC ti mú ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá lórí ẹ̀sùn jìbìtì lílù lórí ayélujára ní Oyo
- Kíni ó lè mú kí ọmọbìnrin sá kúrò nílé láti ìpínlẹ̀ Plateau lọ sí Ekiti?
Egypt Air ni: Inu wa dun pe iya ati ọmọ wa ni alaafia
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu, Egypt Air loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni wọn ti fi iroyin naa lede.
Wọn fi lede wi pe awọn ti fun ọmọ naa ni aṣẹ lati ma wọ ọkọ ofurufu wọn lọfẹ ni gbogbo aye rẹ.
'Ọmọbinrin tuntun jojolo naa ni wọn bi ninu ọkọ ofurufu, ti o si gba tikẹẹti ọfẹ titi aye rẹ lati wọ ọkọ baalu '
Ọkọ ofurufu naa n lọ lati orilẹede Egypt lo si London ni ki iṣẹlẹ naa to waye, ti wọn si tiraka lati lọ si Munich, ni Germany, amọ ọmọ naa wa ki o to di wi pe wọn de ibẹ.
Bakan naa ni ileeṣẹ Egypt Air naa ba iya ati mọlẹbi ọmọ tuntun naa yọ fun ọre ọfẹ ti wọn ri gba lati bi ọmọ naa ni ayọ ati alaafia.

















