Robbers caught sleeping in stolen vehicle: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ọlọ́ṣà sùn lọ nínú ọkọ̀ tí wọ́n jí

Afurasi Adigunjale

Oríṣun àwòrán, @others

Ọwọ ti tẹ awọn adigunjale meji kan ti wọn ni wọn digunjale gba ọkọ lọwọ dẹrẹba kan lagbegbe Ibeji- Lekki.

Dẹrẹba naa ti orukọ re n jẹ Utibe lawọn olopaa ṣalaye pe o n fi ọkọ Toyota corolla rẹ ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ akero igbalode Bolt lagbegbe ileewe ẹkọṣẹ imọ nipa okoowo, Lagos Business cool.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, arakunrin Utibe yii n gbe awọn onibara meji lọ si ibi ti wọn n lọ nigba ti wọn fa irinṣẹ ẹlẹnu mimu kan yọ ti wọn si fi gun un ki wọn to gbe ọkọ rẹ salọ.

Àkọlé fídíò, Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

Iroyin naa fi kun un pe ṣadeede ni ọkọ naa duro ti awọn afurasi odaran naa si ro pe epo lo tan ninu rẹ ni wọn ba kuku fi ẹyin lelẹ pe ki awọn sun ki ọwọ awọn ọlọpaa to ka wọn mọ ibẹ.

Iroyin loju opo ayelujara ọkan lara awọn ọrẹ Utie to lu awo ọrọ yii sitaṣalaye oe nnkan bi agogo mẹsan an ku ogun iṣẹju ni alẹ ọjọ Aiku, Ogunjọ oṣu kẹsan ọdun 2020 ni awakọ naa gunlẹ si ibi ti wọn da pe ko ti wa gbe wọn ki wọn to gun ti wọn si gbe ọkọ rẹ lọ.

Awọn ọdaran naa ko mọ pe ohun elo igbalode tracker wa lara ọkọ naa, ohun ni wọn si fi pana ọkọ naa leyi ti awọn ọdaran naa n ro pe epo li tan ninu ọkọ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ọgbẹni Adejọbi salaye pe wọn ba ake ati ọbẹ kan ti o kun fun ẹjẹ lara wọn.

O ni awakọ Toyota corolla naa ti n gba itọju ni ileewosan kan.