Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba

Ẹyan oríṣi meje ló wa ninu girama ede Yoruba.

Arabinrin Bunmi aya Femi Amao lati ile iwe Graceland Heights School ni agbegbe Wọfun, Olodo ni ilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo ni olukọ wa fun toni.

Ọrọ Ẹyan ni koko girama ti an gbe yẹwo loni.

Ẹyan Asapejuwe ni o maa n sọ fun wa sii nipa ọrọ orukọ.

Eto Akomolede ati Asa yii n waye lati ọwọ BBC Yoruba pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ Onimọ Yoruba YSAN ati apapọ ẹgbẹ Akomolede Naijiria.

Oriṣi ẹyan meje to wa ni olukọ Bunmi Femi Amao kọ wa loni.

Eyan Ajorukọ

Ẹyan Aṣapejuwe

Eyan Asorukọ

Eyan Atọka Aṣafihan

Eyan Aṣonka

Eyan Arọpo Orukọ

Eyan Afarajorukọ

Eyan Awẹ gbolohun Afarahe Aṣapejuwe.