Increment in bread price: Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀

Buredi

Oríṣun àwòrán, Google

Awọn olugbe ilu Abuja ati Eko ti ke gbajare sita lẹyin ti ọwọngogo burẹdi gbode kan.

Awọn oniburẹdi gunle iyanṣẹlodi lẹyin ti iye owo iyẹfun, suga ati awọn awọn ohun elo miran wọn si.

Awọn to n ta burẹdi lẹgbẹ titi naa faragba ninu iyanṣẹlodi yii, eleyii to fa ọwọngogo burẹdi kaakiri orilẹede Naijiria.

Lara awọn olugbe ilu Abuja sọ wi pe, iyalẹnu lo jẹ fun awọn nigba ti wọn ko ri burẹdi ra jẹ.

O buru to bẹẹ ni opin ọsẹ ni awọn ipinlẹ bii Nasarawa ati Niger nitori iyanṣẹlodi naa bẹrẹ ni Ọjọ Ẹti,ọsẹ to kọja.

Buredi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara awọn oniburẹdi to ba awọn oniroyin sọrọ ni bi o tilẹ jẹpe awọn yoo fopin si iyanṣẹlodi naa, o pọn dandan ki owo burẹdi wọn si.

'' Nibayii, owo iyẹfun ti a n ra ni N10,000 si N12,000, ti da N14,000 bayii.''

''Apo suga ti a n ra ni N11,000 tẹlẹ, ti da N18,000 bayii ati 25-lita ororo ti awọn n ra tẹlẹ ni N8,000 ti da N15,000 bayii.''

Wọn ni ohun to fa ọwọngogo yii ni wi pe, oke okun ni wọn ti n ra awọn eronja yii tẹlẹ, amọ nitori ijọba ti yọ owo iranwọ lori awọn ounjẹ lati okeere, eleyii ti mu ki ohun gbogbo nira fun awọn eniyan.

Ni ipinlẹ Eko bakan naa, awọn oniburẹdi ni ohun to fa ọwọngogo burẹdi ni iye ti wọn ra awọn eronja ti wọn nilo, owo ọkọ to wọn gogo ati bii ijọba apapọ ṣe fi owo kun owo ori ti awọn eniyan n san.

Amọ, Ajọ awọn oniburẹdi ni ipinlẹ Eko ti ni awọn yoo bẹrẹ iṣẹ pada loni, amọ o lera fun awọn lati ta burẹdi ni iye ti wọn n ta a tẹlẹ nitori ọpọlọpọ wọn ti jẹ gbese lori iṣẹ burẹdi tita naa.

Àwón Oníbúrẹ́dì ń gbé ìgbésẹ̀ láti fi kún owó Búrẹ̀dí ní Nàìjírià

Ẹgbẹ awọn oniburẹdi ni Naijiria ti apẹjẹ wọn n jẹ Premium Breadmakers Association of Nigeria (PBAN) ati ẹgbẹ awọn alase ti wọn n jẹ Association of Master Bakers and Caterers of Nigeria ti yari fun ijọba Naijiria lori ọwọngogo ohun jijẹ laisko yii.

Bread

Oríṣun àwòrán, Twitter/OkayAfrica

Wọn kede ni ipinl\e Eko pe alekun yoo ba iye owo burẹdi ati awọn ohun jijẹ ti wọn fi iyẹfun ati ṣuga ṣe laipẹ nitori pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati mu ẹkunwo naa di ajumọṣe.

Ogbẹni Tosin Jemide to jẹ Aarẹ ẹgbẹ PBAN ni Naijiria sọrọ lori iṣoro ti awọn ọmọ ẹgbẹ n koju lẹnu oko owo naa bayii.

Ṣaaju ni awọn ọmọ Naijiria kan ti pariwo pe owo burẹdi ti le sii nigboro ati pe kii ṣe ounjẹ mẹkunnu mọ.

Jemide ni owo ti awọn ọmọ ẹgbẹ n ra Suga ati iyẹfun lasiko yii ti kuro ni keremi lati nkan bii oṣu mẹfa sẹyin lo ti n gbowo lori siii lọsẹẹsẹ.

O ni koda, awon ohun eelo lati fi ṣe burẹdi miran yatọ si ṣuga ati iyẹfun gan an kọja bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Mistura Oseni Akintunde: Ara múmú kìí ṣe oríṣun ìfipábánilòpọ̀, ìran àwòjù ló ń fà á

Aarẹ naa ni orin o to gẹ ni ẹgbẹ mejeeji n kọ lasiko yii fun ijọba.

O ni asiko ti to ki ijọba pese iranlọwọ fawọn oniṣe burẹdi ki ara le rọ tẹru tọmọ.

Ẹgbẹ yii tu bẹnu atẹ lu bi erongba ijọba lati ọdun 2012 ko ṣe tii so eso rere di asiko yii.

Bread

Oríṣun àwòrán, @Kitchnbutterfly

O ni bẹẹ awọn oniburẹdi san ida mẹẹdogun ti ijọba n beere fun owo idagbasoke ki ijọba to le mu idagbasoke ba awọn oniburẹdi.

Ni ipari, ẹgbẹ mejeeji parọwa fun awọn ara ilu lati murasilẹ lati maa ra burẹdi ni owo to le diẹ si ti atẹyinwa ni eyi ti kii ṣe ẹbi awọn oniburẹdi rara.