Buhari: Àwọn ọ̀dọ́ ní kò rọrùn láti ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn láìsí ohun èèlò ìgbàlódé

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kesi awọn ọdọ lati mura giri, ki wọn si gba ọna oko lọ nitori eto ọgbin ni ọna abayọ si iṣoro Naijiria.
Aarẹ Buhari sọ eyi ni ibi ipade Ajọ to n risi ipese ounjẹ, National Food Security Council (NFSC) to waye ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020.
O ni ijọba oun ti kan ni kanpa fun Banki apapọ Naijiria lati fofin de tita owo ilẹ̀ okeere lowo pọ́ọ́ku fun awọn to ba fẹ ra ohun elo ogbin ati ounjẹ lati okeere.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àlàyé rèé lórí bí mo ṣe fi ọsàn híhó fẹ́ ìyàwó mi"
- Wo àmì márùn-un tí o fi le mọ ẹni tó fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀
- Típà tẹ dẹ́rẹ́bà pa ní Epe
- Ọwọ́ tẹ ọkùnrin kan ní pápákọ̀ òfurufú l‘Eko tó ń kó ike ATM 2,886 lọ si Dubai
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ìjọba Kwara fẹ́ sọ orúkọ Rashidi Yẹkini di mánigbàgbé
- Ọ̀kẹ àìmọye ẹ̀rọ àyẹ̀wò káàdì olùdìbò jóná mọ́lé l' Ondo
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
Bakan naa ni aarẹ fikun wi pe, ki awọn ọdọ to ba fẹ ṣiṣẹ gba oko lọ lati lọ ṣe iṣẹ ọgbin.
Amọ ijọba ko laa kalẹ boya eto ọgbin oni ọkọ ati ada ni tabi ti ọna igbalode.
A ti ṣiṣẹ agbẹ lorilẹede Niajiria ko dẹrun rara nitori aisi iranwọ - Kehinde Olufemi
Ọdọ to n ṣiṣẹ Agbẹ lorilẹede Naijiria, Kehinde Olufemi ti wa fesi si ohun ti aarẹ Buhari sọ wi pe, ki awọn ọdọ lọ ma a ṣiṣẹ ọgbin gẹgẹ bi ọna abayọ si airiṣẹse ni Naijiria.
Olufẹmi, lasiko to n ba BBC sọrọ ni, o ṣoro fun ọdọ lati ṣe iṣẹ agbẹ ni Naijiria nitori ko si iranwọ fun wọn.
O ni ko dẹrun fun awọn ọdọ lati ma a lo ọkọ ati ada lati lọ wa ebe, amọ ti wọn ba ri iranwọ to peye, wọn le ṣe iṣẹ oko ni ọna igbalode ti wọn yoo si ri ere nibẹ.

Olufẹmi ni anfaani pupọ wa ninu iṣẹ agbẹ ni Naijiria nitori ilẹ to dara wa ni Naijiria ati oju ọjọ to sunwọn fun eto ọgbin.
- Àwọn dókítà Nàìjíríà ti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì wọn
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Gbèsè Nàìjíríà ti lé ní 18 tírílíọ́ọ́nù lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Buhari- DMO
- Wo bí iṣẹ́ abẹ wákàtí mẹ́fà, tí wọ́n fi dóòlà ẹ̀mí ìjàpá tí ọkọ̀ tẹ̀, ṣe lọ
- Kò sóhun tó ń jẹ́ ‘Captivus’ nílẹ̀ Oodua, mágùn ni mágùn ńjẹ́ - Babaláwo
- Wo àwọn obìnrin abúlé kan tó dáwó ra ọkọ̀ láti máa gbé aláboyún lọ ilé ìwòsàn
''Eto ọgbin ti ran Naijiria lọwọ nigba kanri, yoo tun ran wa lọwọ ti ijọba ba ṣe oun to tọ fun awọn ọdọ''
''Ijọba gbọdọ pese awọn ẹrọ igbalode bii eleyii to n yọ okuta kuro ninu irẹsi abẹle ati bẹẹ bẹẹ lọ''
''Ko dara bii Naijiria ṣe ni awọn eso ọgbin to pọ janturu, amọ ti ko si ohun elo igbalode lati yii awọn ohun ọgbin yii pada si oun jijẹ abi ohun ti awọn eniyan nilo ni ojoojumọ''

Bakan naa ni ọdọmọde agbẹ yii fikun wi pe ọpọlọpọ iṣẹ lo wa ninu ẹka agbẹ to fi mọ rira ati tita, abi kiko ounjẹ lọ si oke okun.
Olufemi naa wa gba ijọba ni imọran lati maṣe daamu awọn ọdọ nitori iya ni yoo jẹ ki awọn ọdọ ṣe iṣẹ agbẹ lai fun wọn ni ohun iranwọ.
''Ẹni to ba fẹ ra ounjẹ tabi oun ọgbin lati ilẹ okeere gbọdọ ṣetan lati san owo rẹ''
Onimọ nipa eto idokowo ni Naijiria, Temitope Kolawole ti sọ wi pe yoo lẹra fun awọn eniyan to n ra ounjẹ ati nkan ọgbin lati oke okun nigba ti ijọba ti kọ lati ta owo ilẹ okeere fun wọn mọ ni owo pọọku mọ yii.

Oríṣun àwòrán, Others
Tẹmitopẹ ni awọn ẹlomiran tilẹ ma n lọ ọna yii lati fi ra owo ile okeere, ti wọn a si ta a ni iye owo gọbọi fun awọn ẹlomiran.
Nitori naa, ẹni to ba fẹ ra ounjẹ lati ilẹ okeere gbọdọ ṣetan lati san owo lori rẹ.
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Alámì ẹ̀yẹ Scrabble Paul Sodje àti ọ̀rẹ́ rẹ́ kú lásìkò tó fẹ́ lọ́ sanwó ìdóòlà ẹ̀mí àbúrò rẹ̀, tí afurasí darandaran jí gbé
- Ìjàmbá iná míràn tún wáyé ní pápákọ̀ ojú omi Beirut
- Femi Fani-Kayode sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Tinubu tori kò dìde kí Ooni
''Eyi yoo fun awọn eniyan laaye lati bẹrẹ si ni ran nkan ounjẹ labẹlẹ, eleyii ti yoo mu ki a bẹrẹ si ni pese awọn oun ti a n jẹ ati eyi ti a n wọ''
Bakan naa ni o kesi ijọba lati lọ owo ti ijọba ba ri lori igbeṣẹ yii lati pese owo iranwọ fun awọn onisowo ati agbẹ kekeeke labẹle.
Agenda 2050: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìgbìmọ̀ tuntun tí Buhari gbé kalẹ́ lórí ìdàgbàsókè Nàìjíríà
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ owo yiya ni Naijiria, Debt Management Office, DMO, ti sọ pe iye gbese ti Naijiria jẹ lapapọ bayii ti le ni tiriliọnu mọkanlelọgbọn.
To n tumọ si pe lati nnkan bi ọdun marun un ṣeyin labẹ iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari, gbese tun Naijiria tun pele si ni pẹlu nnkan bii tiriliọnu mejidinlogun naira.

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu
Eyii tun n tumọ si pe iye gbese ti Naijiria jẹ ga soke sii ni ida aadọjọ.
- Kò sóhun tó ń jẹ́ ‘Captivus’ nílẹ̀ Oodua, mágùn ni mágùn ńjẹ́ - Babaláwo
- Wo àwọn obìnrin abúlé kan tó dáwó ra ọkọ̀ láti máa gbé aláboyún lọ ilé ìwòsàn
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Alámì ẹ̀yẹ Scrabble Paul Sodje àti ọ̀rẹ́ rẹ́ kú lásìkò tó fẹ́ lọ́ sanwó ìdóòlà ẹ̀mí àbúrò rẹ̀, tí afurasí darandaran jí gbé
Ẹwẹ, yatọ si awọn gbese ti Naijiria ti jẹ, ọrọ aje ti dẹnukọlẹ, bẹẹ ni nnkan ko ṣenu ire fun ọpọ ọmọ Naijiria nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Muhammadu Buhari
Ṣugbọn ijọba apapọ ti sọ pe ohun yoo sa gbogbo ipa oun lati ri pe nnkan pada bọ sipo, ati pe igbe aye dẹrun fun awọn ara ilu.
Eyii lo mu kii Aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ igbimọ kan, eyii ti yoo ṣabojuto bi ọrọ aje Naijiria yoo ṣe gberasọ pada ko to di ọdun 2050.
Lara awọn ti yoo maa tukọ igbimọ ọhun ni ọgbẹni Atedo Peterside ati minisita eto iṣuna, Zainab Ahmed.
Ki ni afujusun ati anfani Vission 2050 yii?
Lara awọn nnkan to sọ nigba ti Aarẹ Buhari n kede igbimọ naa lọjọ kẹsan an, oṣe kẹsan an, ọdun 2020 ree:
Lati yọ ọgọrun miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ laarin ọdun mẹwaa sasiko yii, paapaa lẹyin ti banki agbaye ti sọ asọtẹlẹ pe Naijiria yoo jẹ ọkan pataki lara awọn orilẹ-ede ti eeyan rẹ yoo pọju lagbaye ko to di ọdun 2050.
Aarẹ ni o ṣe pataki lati ṣe awọn eto ti yoo jẹ itẹsiwaju 'Vission 2020' eyii ti yoo wa sopin lọdun yii.
Bakan naa ni Aarẹ tun paṣẹ fun igbimnọ naa lati gbe awọn eto ti yoo rọrun lati tẹlẹ kalẹ, paapaa lasiko ti awọn eeyan to wa ninu igbimọ ọhun ba pari saa wọn tan.
Buhari sọ pe ti igbimọ naa ba ṣe iṣẹ rẹ bi iṣẹ, nnkan yoo yipada si rere fun awọn ọmọ Naijiria.
Ṣugbọn ero awọn ọmọ Naijiria ṣọtọtọ lori agbekalẹ igbimọ vission 2050 naa, bi awọn kan ṣe n sọ pe ki Buhari kọkọ ṣe awọn nnka to ṣeleri lasiko to n ṣe ipolobgo ibo, lawọn miran n sọ pe awọn yoo maa wo ibi ti ọrọ ọhun yoo ja si.
Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?
Buhari: Ẹ̀yin Mínísítà, ẹ lọ gbe ìjọba mi níjà lọ́dọ̀ aráàlú pẹ̀lú àfihàn àṣeyọrí mi

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sisọ loju rẹ pe oun ni ori n ta julọ nidi wahala igba gbogbo to n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran.
Bakan naa lo fikun pe wahala yii buru to bẹẹ to fi n mu awujọ agbaye lomi, ti aarẹ Donald Trump tilẹ Amẹrika si bi oun nigba kan ri pe ki lo de toun fi n pa awọn Kristẹni.
Buhari sisọ loju ọrọ naa lọjọ isẹgun nibi opin ipade agbeyẹwo awọn minisita to waye nile ijọba nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba fẹ́ kọ́lé 300,000, pẹ̀lú ìrànwọ́ fún àgbẹ̀ 4m láti mú àdínkù bá ìṣẹ́ - Osinbajo
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Coronavirus ti fa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní ìpínlẹ̀ Eko, Kano, Rivers àti Abuja- NBS
- Àwọn èrò yarí lórí sísan owó àyẹwò covid-19 bí bàálù ilẹ̀ òkèèrè ti ba s'Abuja lẹyìn oṣù márùn ún
- Ẹ wo ààrẹ orílẹ̀-èdè tó ń ṣèdárò Ẹja akóredé tó d'olóògbé
- Àbá àpérò 2014 CONFAB lojútùú sí àtúnṣe ìwé òfin Nàìjíríà- Afenifere sáwọn sẹ́nẹ́tọ̀
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun fún àwọn ọmọ ilé ìwé ní ìgbéga sí kílààsì tó kàn láì ṣe ìdánwó nítori Covid-19
Aarẹ wa pasẹ fawọn minisita pe ki wọn jade lọ maa gbe ijọba oun nija lọdọ araalu nipa sise afihan awọn aseyọri alailẹgbẹ ti oun ti se lori aleefa.
Buhari wa n bi awọn minisita naa pe to ba jẹ pe awọn ni Trump kọju ibeere naa si, ki ni wọn yoo se nitori ibeere naa ba oun labo.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ o ni oun fun Trump lesi pada lai jẹ ko mọ ero ọkan oun, toun si ni ija agbẹ atawọn darandaran ju ọjọ ori oun gan lọ, ka to wa sọ ti Trump, tori mo si fi ọdun diẹ ju lọ.
Buhari wa fikun pe, awọn asaaju saa isejọba alagbada akọkọ lo tii pegede julọ ti Naijiria tii ni.
O ni oun ti sọ fun minisita feto ọgbin lati hu akọsilẹ ofin ijọba nibẹrẹ ọdun 1960 jade eyi to sọ nipa awọn oju ọna tawọn maalu le gba.
"Pẹlu ayipada oju ọjọ ati ba se n pọ si, ati asa awọn darandaran to jẹ pe to ba ni maalu aadọta, ti wọn jẹ koriko, gbogbo orisun omi ti wọn ba ri ni wọn yoo tọ lai naani ẹni yoowu to ni wọn."
"Nitori naa, darandaran to ba fun maalu rẹ laaye lati lọ sinu oko oloko ni ijọba yoo gbe lọ sile ẹjọ. Agbẹ yoo sọ iye owo ire oko ti maalu naa jẹ, ti darandaran naa ko ba si le sanwo ọhun, wọn yoo ta maalu naa.
Buhari ni awọn asaaju to jẹ lẹrin saa ijọba alagbada akọkọ lo ba ofin naa jẹ, ti wọn si gba isẹ awọn darandaran se.
Alásè Buhari kú, Buhari ń ṣọ̀fọ̀

Oríṣun àwòrán, @GarShehu
Ẹyin eeyan wa, aṣe awọn alagbara naa a maa mọ iyi ounjẹ to gbamuṣe.
Abi ki ni ka ti sọ ti aarẹ Muhammadu Buhari bayii to ni oun n ṣọfọ alase oun.
Buhari Nalado Sandamu to jade laye lẹyin to se ounjẹ adidun si ẹnu aarẹ Buhari fun ọgbọn ọdun gbako.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ aarẹ orilẹ-ede Naijiria gbe jade eyi ti amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Garba Shehu fọwọ si, aarẹ Buhari ni "mo ti padanu olutọju mi to dara to si lootọ."
Buhari ni alase rẹ ọhun ti ọpọ mọ si 'Commander' jẹ ẹni to tọju ile oun ni ilu Daura nipinlẹ Katsina daadaa ti ko si jẹ ki iya jẹ idile oun.
Ni ileewosan nla Aminu Kano teaching Hospital, AKTH to wa nilu Kano ni o dakẹ si ni ọjọ Aje.
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, aarẹ ti gbe igbimọ kan dide lati lọ ba awọn ẹbi alase rẹ naa kẹdun.
Lara awọn to wa ninu igbimọ ti aarẹ Buhari gbe dide yii ni amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ itọju ile, Sarki Abba, Garba Shehu to jẹ amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, oludari eto ati ilana gbogbo ni ile ijọba l'Abuja, Ambasadọ Lawal Kazaure.
Ki Olorun dẹlẹ fun ẹni to lọ ni adura aarẹ.















