EFCC /FBI: Ọwọ́ EFCC / FBI tẹ àwọn gbájúẹ̀ 167, wọ́n gbà owó púpọ̀ padà

Ajọṣepọ EFCC ti Naijiria ati FBI ti America ti n bi eso irapada owo gọbọi A ń fikunlukun pẹ̀lú FBI láti mú àwọn "Yahoo Boys" tó kù- EFCC.
Ajọ to n gbogun tiwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFFC ati akẹgbẹ wọn FBI lati ilẹ Amerika ti kede aṣeyọri ajumọṣepọ wọn ti wọn pe ni 'Operation Rewire'.
Lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Eko ni wọn jabọ pe awọn ti mu awọn onijibiti orile-ede Naijiria mẹtadinlaadọsan an EFCC gba ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ 30, òògùn ìbilẹ̀ àti ọ̀pọ̀ fóònù lọ́wọ́ àwọn gbájúẹ̀.
Bakan naa ni wọn ni awọn ri owo apapọ Naira ati dọla to le ni miliọnu mẹtalelaadọjọ gba pada lọwọ wọn, iyẹn $169,000 àti N92, 000, 000.
Gẹgẹ bi ohun ti akọroyin wa jabọ lati ẹnu aṣoju FBI ni Naijiria, ọgbẹni Uche Amdi ni ọwọ tẹ awọn eeyan wọn yi lẹyin ti wọn ti ṣaaju fẹsun kan awọn eeyan ọgọrin kan.
Ninu awọnti wọn fẹsun kan ni a ti a ri ọmọ Naijiria mẹtadinlọgọrin ninu wọn.
Amdi ko sọ ni pato iye ọmọ Naijiria ti wọn ti ri mu ninu awọn mẹtadinlọgọrin ti wọn fẹsun kan naa.
Amọ ṣa, o ṣalaye pe lara awọn ti awọn mu to wa ni Naijiria ni awọn yoo ko wọn lọ si ilẹ Amẹrika nitori pe awọn ọmọ Amẹrika wa lara awọn ti wọn lu ni jibiti.
Ẹwẹ, o fikun ọrọ rẹ pe o le ni ẹjọ ẹgbẹrun meji to nii ṣe pẹlu lilo akoto ifiweranṣẹ awọn eeyan lori ayelujara lọna aitọ ti awọn n tọ pinpin rẹ lati dun 2018.
Awọn ẹjọ wọn yi ti mu ki awọn eeyan padanu owo to le ni biliọnu meji dọla.













