Àrà kengé! Egbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà sàn N5,000 láti rà agbábọ́ọ̀lù tó n gbowó julọ

Ibrahim Iriyos
Àkọlé àwòrán, Àrà kengé! Egbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà sàn N5,000 láti rà agbábọ́ọ̀lù tó n gbowó julọ

Ẹ wo oju agbabọọlu yi daadaa, nitori igba ti yoo ba bẹrẹ si ni jẹ goolu.

Idi ni pe atamatase ti ẹ n wo yi ni agbabọọlu ti wọn n san owo julọ fun ni ilu rẹ.

Bẹẹni, ko si ẹni to n gba owo to to Ibrahim Salisu Iriyos ni Gano, ijọba ibilẹ Dawakin Kudu ni ipinlẹ Kano, ninu awọn agbabọọlu to wa nibẹ.

Koda, ni akọsilẹ ere bọọlu lorile-ede Naijiria, oun ni akọkọ agbabọọlu ti wọn yoo san owo tabua fun ni ilu rẹ.

Ẹ fẹ mọ iye to gba abi, lalai deena pẹnu, Ibrahim Salisu Iriyos gba ẹgbẹrun marun un Naira gẹgẹ bi agbabọọlu ti o gba owo julọ fun ẹgbẹ Super Stars.

Lọwọ ẹgbẹ Aston Villa Gano ni Super Stars ti ra Salisu Iriyos lati ipele liigi keji ni iye owo ẹgbẹrun marun un.

Atamataṣe naa to jẹ goolu pupọ fẹgbẹ rẹ fifẹ han si pe oun fẹ ṣoju ẹgbẹ to wa ni ipele ikini.

Koda, o dara pọ mọ ikọ Super Stars lasiko tawọn akẹgbẹ rẹ n sinmi, ti o si mu ki wọn mọ wi pe ẹlẹsẹ ayo ni Salisu.

Idin Gano ni orukọ alaga ẹgbẹ Gano, oun si lo lewaju idunadura pẹlu akọnimọọgba Aston Villa Abba Alasan Super Stars ti wọn fi gba lati san owo naa fun Salisu.