Kí ló mú Sanusi kọrin bù Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Ganduje?

Oríṣun àwòrán, @Dawisu
Wọn fi ẹsun kan Sanusi pe o kọrin bu Gomina lootọ, amọ kii ṣe Emir Sanusi Lamido Sanusi la n sọ.
Olorin kan nipinlẹ Kano ti orukọ rẹ n jẹ Sanusi Abdullahi, lo ri ibinu ọlọpaa lori ẹsun pe o kọrin bu Gomina Abdullahi Ganduje.
Lati ọjọ abamẹta ni ileesẹ ọlọọpa ni Sanusi ti wa ni ahamọ lọdọ awọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Fọnran fidio orin naa ti n ja rainrain loju opo Whatsapp. Ninu rẹ, a ko ri oju ẹni to kọrin naa nitori pe iha ati ẹyin lo kọ si oju kamẹra.
Eyi si ti mu ki awọn eeyan maa beere pe, bawo ni ọlọpaa ṣe mọ pe Sanusi lo kọrin bu Gomina, nigba ti wọn ko ri oju rẹ.
Amọ ṣa, agbẹnusọ ọlọpaa nilu Kano, DSP Abdullahi Haruna sọ fun BBC pe, awọn ti wọ Sanusi lọ si iwaju adajọ nibi ti yoo ti wi tẹnu rẹ.
''Mi o le sọ bo kọrin bi ko kọrin, amọ a ti gbe lọ si ile ẹjọ lati wi tẹnu rẹ''

Lati igba ti wọn ti mu Abdullahi, awọn mọlẹbi rẹ ti n ja fitafita lati ri pe wọn tu silẹ.
Ọrọ gbọna mi yọ lọjọ Iṣẹgun, nigba ti iroyin lu sita pe awọn ọlọpa ti mu olorin to kọ orin naa gangan, nibi ti o ti n di ẹru lati sa nilu.
Awọn mọlẹbi Abdullahi lero pe eleyi yoo mu ki wọn tu silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbọn rẹ, Jamilu Abdullahi to ba BBC sọrọ ni, awọn yoo wa owo itanran lọdọ ọlọpaa lẹyin ti wọn ba tu silẹ.
Jamilu salaye pe, ''wọn mu Sanusi ni iṣoju iyawo rẹ lọjọ abamẹta. Iṣẹlẹ yii fọwọ bani lẹmi tori pe, oun kọ lo kọ orin to n ja rainrain yii''
Iṣẹju mẹsan gbako ni ẹkunrẹrẹ orin naa, to si ni awọn ọrọ eleyi to bẹnu atẹ lu Gomina Ganduje.












