Iná Ibadan: Àwọn olùgbé inú ilé ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́

Ijamba nla ṣẹ ni adugbo oke Ado nilu Ibadan lowurọ ọjọ isẹgun nigba ti ile alaja kan gbina.
Iroyin kan ti ko fidi mulẹ, to n ja rainrain lori ayelujara salaye pe, ọmọde kan to n se ounjẹ lasiko ti iya rẹ n wo ere lori mohunmaworan lọwọ, lo se okunfa ijamba ina naa.
Awọn olugbe ile naa ṣe alaye fun ikọ BBC Yoruba wi pe, ina ọba to de lojiji si adugbo naa, lo ṣokunfa iṣẹlẹ agbọgbarimu ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lasiko ti ikọ iroyin BBC Yoruba se abẹwo si ile to jona naa, a ri pe rẹrẹ run nibẹ, ti ọpọ dukia si sofo, bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹmi kankan to sofo lasiko isẹlẹ naa.

Lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn olugbe inu ile naa rawọ ẹbẹ si awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ ilẹ yii lati se iranwọ fun wọn, lori awọn dukia wọn to jona mọle.Wọn salaye pe, awọn gbiyanju lati sare ko awọn ohun elo to n bẹ ninu ile naa jade lasiko eefin bẹrẹ sini ru, ṣugbọn pupọ ninu awọn ohun elo naa ni ina ọmọ ọrara ti sọ di eeru, ki awọn aladugbo to gbe omi ati awọn ohun elo mii ti wọn fẹ fi pa ina to de.

Pupọ ninu awọn olugbe ile naa lo padanu owo, awọn ohun elo to n lo ina ijọba, ati ọpọlọpọ dukia sinu iṣẹlẹ naa.








