Ìwádìí ilé aṣòfin foríṣánpọ́n lórí ẹ̀sùn Gómìnà Ganduje

Oríṣun àwòrán, DWasiu
Alaga igbimọ ẹlẹni meje nile aṣofin ipinlẹ Kano to n ṣewadi Gomina Abdullahi Ganduje sọ pe awọn ti dawọ iṣẹ duro na lori ọrọ rẹ.
Aṣofin Baffa Dan Agundi sọ fun BBC pe ko tọ si awọn lati ṣaigbọran si aṣẹ ti ile ẹjọ pa pe ki wọn jawọ ninu iwadi naa patapata.
O ṣalaye pe "a ko le ṣe ohunkohun lori ẹsun owo ẹyin gbigba ti 'wọn fi kan gomina Ganduje' mọ ayafi ti ile ẹjọ ba pada gba wa laaye".
Awọn eniyan kan ni ipinlẹ Kano n fura pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ to gbe ọrọ lọ sile ẹjọ lati da awọn aṣofin lọwọ kọ, jẹ awọn oloṣelu lo n fun wọn ni owo lati le da iṣẹ iwadi naa ru.
Ọsẹ yii lo yẹ ki iṣẹ iwadii ti igbimọ naa n ṣe wa s'opin, ki ile aṣofin to wa sọ eero rẹ lorii boya Gomina Ganduje jẹbi tabi ko jẹbi.
Ṣaaju asiko yii ni ọkunrin kan, Muhammad Zubair ati ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Lawyers for Sustainable Democratization of Nigeria, gbe ọrọ lọ sile ẹjọ pe awọn aṣofin ọhun ko gbọdọ ṣewadi Ganduje.
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹwa, ni ile aṣofin ipinlẹ naa gbe igbimọ ẹlẹni meje kalẹ lati ṣewadii awọn fidio kan to fihan pe Gomina Ganduje n gba owo ẹyin lọwọ awọn kọngila.












