Super Eagles kò rántí kó ohun eèlò ìgbábọọlu wọn dání

Oríṣun àwòrán, @NFF
Agbẹ ti lọ soko idije bẹẹ ko ranti ọkọ ni ọrọ Super Eagles loni.
Egbẹ agbabọọlu Super Eagles ti ilẹ Naijiria to lọ si orilẹ-ede Ukraine lati gba boolu ọlọrẹjọrẹ ninu eyi ti wọn ti gbagbe eroja wọn.
Super Eagles ti wọn jẹ agbabọọlu àgbà fun ilẹ wa ni wọn ti gunlẹ si ilu Dnipro sugbọn ti wọn ko ranti ko awọn ohun eelo igba bọolu wọn dani.
Abẹnugan fun eto are bọọlu fún Super Eagles, Ademọla Ọlajiire lo fi iroyin naa lede ni ọjọ lsinmi ọsẹ yii.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn agbabọọlu mẹfa miran ni wọn tun n reti baagi ti ohun eelo wọn wa gẹgẹ bi igbaradi yoo ṣe bẹrẹ ni ọjọ Iṣẹgun ni pẹrẹwu.
Wọn ni lẹyin ti ọkọ ofurufu to gbe wọn balẹ tan naa ni wọn rii pe ko si ẹru wọn kankan ninu ọkọ ofurufu ọhun
Olori awọn ti wọn jọ kọwọ rin de ilu Dnipro, ni orile ede Ukraine, Dayọ Achor wi pe awón alaṣẹ ọkọ ofurufu Turkey yoo ṣe iranlọwọ to yẹ lati ko ẹru naa pada wa.
Dayọ tẹsiwaju pe, asọye to muna doko ti wa laarin ajọ NFF ti ilẹ Naijiria ati alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa lati tete ko awọn ohun eelo naa pada de saaju ọjọ lsẹgun.
Idije ọjọ Isẹgun yii lo maa bẹrẹ ni bii agogo meje abọ aṣaalẹ lori papa iṣere nla ti ilu Dnipro.












