Lautech: Ìjọba Ọ̀ṣun ní òun kò jẹ òṣìṣẹ́ fásitì náà lówó oṣù

Oríṣun àwòrán, @Awesome206
Ijọba ipinlẹ Ọsun ti fariga, to si tako ẹsun ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde fi kan ijọba ipinlẹ naa pe o tun ti kuna lati san owo osu awọn osisẹ fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintọla, LAUTECH.
Atẹjade kan ti alakoso feto iroyin fun ijọba ipinlẹ Ọsun, Adelani Baderinwa fisita lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe Makinde ko ni awọn akọsilẹ to peye lori ọrọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ ọdún méjìlá ni mo ti ń ṣe bàálù, ọkọ̀, ilé àti ọkọ̀ ojú omi - Ọdọ́mọdé ‘Engineer’
- Ìkọlù sáwọn àjèjì kò tíì tán ní South Africa, ètò ń lọ láti kó ọmọ Nàíjíríà wálé
- Ajé ò! Ẹ wo fídíò òfò àti àdánù tó wáyé níbi ìkọlù sáwọn àjèjì ní South Africa
- "A ti nílé, dúkìá àti ẹbí ní South Africa, àwa kò ṣetán láti padà sílé"
Bẹẹ ba gbagbe gomina Seyi Makinde lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ lasiko ayẹyẹ ọgọrun ọjọ to gori oye, lo fẹsun kan ijọba ipinlẹ Ọsun pe o kuna lati san owo osu awọn osisẹ fasiti Lautech bẹrẹ lati idaji ọdun yii, gẹgẹ bo se wa ninu adehun.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Baderinwa, nigba to n fesi ni "Ijọba ipinlẹ Ọsun ko kuna ri rara ninu awọn ojuse rẹ lati ọdun mọkandinlọgbọn ti wọn ti da silẹ, to si n se ojuse to tọ si gẹgẹ bii ipinlẹ alajọni fasiti Lautech lai naani pe ijọba ipinlẹ Ọyọ n yan awọn jẹ."
Atẹjade naa wa kesi gomina ipinlẹ Ọyọ lati lọ ka awọn akọsilẹ to tọ nipa bi wọn se n san owo osu awọn osisẹ fasiti Lautech, bi o tilẹ jẹ pe o han si awọn pe Makinde ti seleri lasiko ipolongo ibo rẹ pe oun yoo sọ fasiti naa di ti ipinlẹ Ọyọ nikan.

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetola
O wa rọ gomina Makinde lati mase gunle iwa ibanilorukọjẹ abi igbiyanju lati ru awọn osisẹ fasiti Lautech laya soke, to fi mọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lapapọ.
O ni awọn ọrọ rẹ naa lee jẹ ki wọn maa gboju agan sijọba ipinlẹ Ọsun abi gomina Adegboyega Oyetọla, ẹni to maa n tete kọbi ara sawọn ọrọ to ba jẹ mọ ti osisẹ.








