Robert Mugabe: Àkójọpọ̀ àwọn ọrọ Mugabe tó sọ àti eléyì tí kò sọ tí a kò lè gbàgbé

Oríṣun àwòrán, KELD NAVNTOFT
Iru awọn ọrọ apanilẹrin wo ni wọn ni Mugabe sọ ati eleyi ti ko sọ ti ẹ ko le gbagbe?
Ibeere ree ti a fẹ gbiyanju lati mu idahun wa si fun yin toun ti bi awọn eeyan ṣe n ṣe iranti Robert Mugabe, aarẹ orileede Zimbabwe to ku.
Ṣọrọ sọrọ ti ọrọ da lẹnu rẹ ni aarẹ Robert Mugabe, to si maa n tako awọn ijọba ilẹ okeere alawọ funfun ninu ọrọ rẹ. Robert Mugabe di ero ọrun
Pupọ ninu awọn igba to ba n sọrọ, awọn oniroyin a ma fẹ tẹti si ọrọ rẹ nitori a ma sọko ọrọ ti awọn eeyan a ma fẹ gbọ.
Ninu awọn ọrọ rẹ, o ni awọn eleyi to jẹ otitọ ati awọn mii ti ko sọ, ṣugbọn ti awọn eeyan ni oun lo sọ.
Awọn wo lo ko awọn ọrọ ti ko sọ yi jọ?
A ko le sọ pato pe lagbaja tabi tamẹdun lo ko awọn ọrọ yi jọ ṣugbọon loju opo ayelujara paapa Facebook, wọn pọ daada.
Lori awọn opo kan to mu niṣẹ lati ma fi awọn ọrọ wọn yii da awọn eeyan lara ya, iye eeyan to n fi ọkan tẹle awọn oju opo yii ko kere rara.
Diẹ ninu awọn ọrọ naa re e:

Oríṣun àwòrán, Facebook/mugabequotes1

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/mugabequotes1

Oríṣun àwòrán, Facebook/mugabequotes1
Ki lo mu ki awọn eeyan fẹran awọn ọrọ wọn yii:
Awọn to ko ọrọ wọn yii jọ loju opo ayelujara naa jẹwọ pe, wọn kii ṣe ọrọ Mugabe ni tootọ.
Ṣugbọn nitori wpe awọn eeyan mọ Mugabe si ẹni to ma n da apara lọpọ igba, ko nira fun wọn lati so ọrọ ẹfẹ wọnyii mọ lẹsẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/mugabequotes1
A ti pe lọpọ igba, oun ti yoo pa awọn eeyan lẹrin ni wọn ma n wa loju opo ayelujara, ti ọrọ Mugabe yii si ṣe rẹgi iru nkan ti wọn n wa.
Ki a to kasẹ ọrọ wa nilẹ, ẹ jẹ ki a wo awọn ọrọ to jẹ ootọ ti awọn eeyan ko le gbagbe.
Loju opo Twitter Ablaku Dauda fi ọkan ninu awọn ọrọ yii sita:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn mii ninu ọrọ rẹ gẹgẹ bi a ti ṣe ri akọsilẹ fun wọn ree e:












