Robert Mugabe: Inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ló ti dìbò wọlé láti darí Zimbabwe

Aworan Aarẹ Mugabe

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Mugabe nibi to ti n sọrọ nibi ajọdun mẹjidinlọgbọn ti orileede Zimbabwe gba ominira

Gẹgẹ bi olootu ijọba akọkọ to si tun pada jẹ Aarẹ lorileede Zimbabwe, Robert Mugabe pinnu lati mu ijọba awa a rawa wa, to fi mọ ipẹtusaawọ.

Ṣugbọn pabo ni ireti yii jasi lẹyin ominira lọdun 1980, ti iwa janduku, jẹgudujẹra ati ijakulẹ nipa ọrọ aje gbode kan.

Aarẹ Mugabe di alatako awọn ilu okeere paapa julọ ilẹ gẹẹsi, ti Zimbabwe gba ominira lọwọ, Mugabe si pe Gẹẹsi ni ''ọta orilẹede rẹ''

Toun ti bo ti ṣe n dunkoko mọ awọn alatako ati bo ti ṣe n ṣe eto ọrọ aje ilu basubasu, awọn olori orileede Afrika ṣi n gbe lẹyin rẹ.

A bi Robert Gabriel Mugabe lagbegbe ti a mọ tẹlẹ si Rhodesia, lọjọ Kọkanlelogun oṣu Keji ọdun 1924.

Kafinta ni baba rẹ, ti iya rẹ si jẹ ọmọ ẹya ti wọn sọ ede Shona. O kẹkọ nileewe katoliki nibi to ti gboye imọ ijinlẹ ni idi isẹ olukọ.

O jẹ anfaani iwe ẹkọ ọfẹ lọ si yunifasiti Fort Hare lorileede South Africa, to si kawe gboye akọkọ ninu oye meje to pada gba.

O tesiwaju lọ si orileede Ghana nibi ti o ti gba iṣẹ olukọni. Nibẹ ni ọrọ olori Ghana nii, Kwame Nkrumah lori idagbasoke ilẹ Afrika ti wọ lara.

Iyawo akọkọ to fẹ Sally jẹ ọmọ orileede Ghana.

Lọdun 1960 Mugabe pada si Rhodesia. O kọkọ bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ itẹsiwaju ilẹ Afrika pẹlu Joshua Nkomo, ki o to yapa lati lọ jẹ ọmọ ẹgbẹ ti wọn jijọ ṣe idasilẹ ẹgbẹ Zanu, Zimbabwe African National Union.

Ni 1964, lẹyin ti o bẹnu atẹ lu olootu ijọba Rhodesia, Ian Smith ati ijọba rẹ, wọn mu Mugabe ti wọn si fi si ahamọ fun ọdun mẹwa, lai laanfani si igbẹjọ.

Aworan Mugabe ati Nkomo nibiipade kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mugabe pẹlu Nkomo lapa osi rẹ lọdun 1960. Awọn mejeeji ko pada wa gbọ ara wọn ye lẹyin ti Zimbabwe gba ominira.

Ọmọ ikoko rẹ ọkunrin salaisi nigba ti o wa lẹwọn, ti wọn ko si jẹ ki o lọ sinku rẹ.

Ni 1973 wọn yan gẹgẹ Mugabe bii olori Zanu toun ti pe o ṣi wa ni ahamọ.

Lẹyin ti wọn tu silẹ, o lọ si Mozambique nibi to ti n dari awọn ọmọ ogun ọlọtẹ lati maa ṣe ikọlu pẹlu ijọba Rhodesia.

Zanu darapọ mọ Zapu ti ṣe Zimbabwe African People's Union, ti Nkomo jẹ olori wọn.

Wọn ri Mugabe gẹgẹ bi olori ti ko gba gbẹrẹ, nigba ti wọn n ṣe idunadura lori fifun Rhodesia lominira.

Lasiko to ṣe abẹwo kan si London lọdun 1976, o sọ pe ko si ọna abayọ kankan si wahala Rhodesia, bi kii ṣe ki wọn fi ibọn yanju rẹ.

Ipẹtu saawọ:

Ṣugbọn oye to ni nipa idunadura mu ki awọn alatako rẹ gan kan sara si. Awọn akọroyin si n pe ni ''ajijagbara onilaakaye.''

Adehun Lancaster House ti wọn buwọlu lọdun 1979 ṣe agbekalẹ iwe ofin tuntun fun orilẹede Zimbabwe to jẹ orukọ tuntun, ti wọn mọ si Rhodesia tẹlẹ, ti o si dajọ idibo akọkọ si osu keji ọdun 1980.

Mugabe du ipo ninu idibo naa labẹ asia ọtọ si ti Nkomo, o jawe olubori ti o si ya ọpọ lẹnu wi pe o fakọyọ.

Aseyọri rẹ mu ki ọpọlọpọ awọn alawọ funfun maa palẹ ẹru wọn mọ, ti awọn alawọ dudu si bẹrẹ si ni jo yagini yojo.

Amọ o fi awọn eeyan lọkan balẹ wi pe, oun yoo ṣe ijọba ti ko ni da apa kan si.

O ni akori ijọba oun yoo jẹ ipẹtu saawọ.

Mugabe nibi to tin sọrọ lọjo ti orileede Zimbabwe gba ominira

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ni ibẹrẹ, Mugabe pinu lati mu opin ba gbogboede aiyede to wa nilẹ

O se alakalẹ eto ijọba rẹ to ti ni oun yoo gba idokowo aladani ati ti ijọba laaye papọ.

Ko pe ko jina ti ọrọ bẹrẹ si ni daru laarin oun ati Nkomo nito ri pe Mugabe n tẹnumọ isejọba labẹ ẹgbẹ oselu kan ṣoṣo.

itLeyin ti wọn ri awọn nnkan ija ni ile kan ti ẹgbẹ Zapu ni, ṣe ni wọn le Nkomo ti wọn ṣẹṣẹ ja ni irawọ walẹ

Mugabe n fi ẹnu lasan sọrọ isejọba tiwantiwa ṣugbọn labẹlẹ o n dunkoko mọ awọn alatako rẹ.

Laarin ọdun 1980 wọn ṣeku pa ọgọrọ awọn ẹya Ndebele ti wọn ri gẹgẹ bi alatilẹyin Nkomo ni agbegbe Matabeland ti Nkomo ti wa.

Ifofinde

Wọn tọka si Mugabe pe o lọwọ ninu awọn ipaniyan wọn yi ti ikọ ọmọ ogun Zimbabwe sẹ ṣugbọn ọrọ naa ko de iwaju adajọ.

Nigba ti wahala pọ, Nkomo gba lati da ẹgbẹ rẹ Zapu pọ mọ Zanu ti o sọ di Zanu-PF ti ko ni alatako mọ.

Lẹyin igba ti o pari ipo olootu ijọba rẹ, Mugabe di Aarẹ ni ọdun 1987 ti wọn si dibo yan si ipo fun igba ẹlẹẹkẹta ni 1996.

Ni ọdun naa ni o fẹ Grace Marufu lẹyin igba ti aarun jẹjẹrẹ pa iyawo rẹ akọkọ.Mugabe ti ni awọn ọmọ meji tẹlẹ pẹlu Grace ti o gba ogoji ọdun lọwọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn bi ọmọ kẹta nigba ti Mugabe di ẹni ọdun mẹ́tàléláàdọ́rin

Awọn alatilẹyin Zanu-PF n dun kukulaja mọ awọn agbẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn alatilẹyin ẹgbẹ Zanu-PF gba ilẹ lọwọ awọn agbẹ

O sẹ awọn aṣeyọri kan pẹlu bi o ti ṣe mu irẹpọ wa laarin awọn eeya alawọdudu ati funfun lawujọ amọ ni ọdun 1992, o mu ofin kan wa ti fayegba ki ijọba fagbara gba ilẹ lọwọ eeyan.

Ohun ti wọn ro pẹlu ofin yi ni pe awọn yoo tun ilẹ ti awọn ẹgbẹrun lọna marundinlaadọta agbẹ alawọfunfun ni pin.

Ni ibẹrẹ ọdun 2000 pẹlu bi galegale ẹgbẹ alatako tuntun Movement for Democratic Change, MDC ti olori awọn ẹgbẹ oṣisẹ Morgan Tsvangirai da silẹ sẹ n pọ Mugabe bẹrẹ si ni halẹ mọ awọn agbẹ to ri gẹgẹ bi alatilẹyin MDC

Awọn alatilẹyin Mugabe gba ilẹ awọn agbẹ alawọfunfun naa ti wọn si pa awọn oṣiṣẹ alawọdudu to n ba wọn ṣiṣẹ.

Iranwọ lati ilẹ okere

Igbesẹ yi mu ki isẹ agbẹ to jẹ ogunagbongbo ọrọ aje Zimbabwe nigba kan ri dẹnu kọlẹ.

Awọn alatako Mugabe ni niṣe ni o pin ilẹ naa fun awọn ore rẹ dipo awọn agbẹ talaka to ni oun fẹ pin fun.

Ko pẹ mọ ti Zimbabwe ti ṣe sun kuro ninu awọn orileede ti ounjẹ pọ yanturu nibẹ si orileede to n tọrọ jẹ.

Aisi ounjẹ yi ko mu ki Mugabe ma wọle ninu idibo to waye lọdun 2000.

Ẹgbẹ oselu rẹ lo jawe olubori pẹlu ipo to poju lọ nile asofin ṣugbọn alatako ni wọn ko jẹ ki awọn eeyan wọn kopa ninu idibo paapa julọ lawọn igberiko

Awọn ọmọ ẹgbẹ MDC mẹta ti wọn ni awọn ọdọ ọmọlẹyin Mugabe ṣe awọn leṣe.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ẹgbẹ MDC fara pa jakejado orileede Zimbabwe lọdun 2008

Pẹlu bi MDC orileede Amerika ati ilẹ Gẹẹsi ti ṣe tako esi ibo yi, Mugabe ati orileede Zimbabwe di ẹni ti aye kẹyin si.

Ajọ orileede Commonwealth naa ni ki Zimbabwe lọ rọkun nile ki o si ma kopa ninu ipade awọn titi ti wọn yoo fi mu atunto ba eto isejoba tiwantiwa wọn.

Losu kaarun ọdun 2005,Mugabe dari bi awọn agbofinro ti ṣe degunle awọn ọlọja rọbi ati awọn to n patẹ sibi ti ko tọ.

O to ẹgbẹrun lọna ọgbọn o'ntaja ti wọn mu ni awọn kereje ilu ti wọn si da awọn ile ti ko ba igba mu wo.

Igbesẹ yi sọ awọn to to ẹgbẹrun lọna ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin di alainile lori.

Aawọ

Ni osu kẹta ọdun 2008,Mugabe fidirẹmi ninu ipele kini idibo Aarẹ ṣugbọn o jaweolubori ninu atundi to waye losu kẹfa lẹyin ti ọgbẹni Tsvangirai kọ lati kopa.

Bi idunkoko mọ awọn alatilẹyin rẹ ti ṣe gbode jakejado orileede, Tsvangirai ni ko ṣe ṣe ki idibo to yanranti waye rara.

Pẹlu gbogbo ohun to n sẹlẹ yi ọrọ aje Zimbabwe ṣi n dẹnu kọlẹ.

Lẹyin ti ọgọrọ eeyan ku latara aarun onigba meji nitori pe ijọba ko ri owo ra kẹmika ti wọn yoo fi toju omi mimu,Mugabe gba lati dunadura lori pinpin ijọba pẹlu alatako rẹ.

Morgan Tsvangirai lẹyin ti Mugabe bura wọle sipo fun gẹgẹ bi olootu ijọba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Adehun pipin agbara naa ko salai ma ni awọn ipenija tiẹ

Lẹyin idunadura fun bi oṣu melo kan,Mugabe bura wọle fun Tsvangirai gẹgẹ bi olootu ijọba ni osu keji ọdun 2009.

Ko jẹ́ iyalẹnu wi pe eto yi ko gunrege pẹlu bi awọn ajafẹtọ ọmọniyan ti ṣe n fapajanu lori bi wọn ti ṣe n fiya jẹ awọnb alatako Mugabe ti o wa ni ahamọ.

Orukọ ọgbẹni Tsvangirai naa sẹbi ẹni baje nitori ibaṣepọ rẹ pẹlu Mugabe toun ti wi pe ko lagbara lati yi ipinu Mugabe pada lori nnkankan.

Idibo ọdun 2013 ti Mugabe ti mu oke lo mu opin ba ibaṣepọ ati pipin agbara ijọba laarin awọn mejeji.

Eyi mu ki Tsvangirai yapa lọtọ.

Toun ti wi pe ẹsun pe wọn sẹ eru nibi ibo naa wa,ko si iwa janduku eleyi to saba ma n waye ninu ibo Zimbabwe.

Awọn to gba ipo lọwọ rẹ

Idibo yi ti Mugabe jawe olubori ninu rẹ lẹni ọmọ ọdun mọ́kàndínláàdọ́rùn ún fidi rẹ́ mulẹ wi pe ko si ẹni to n ba du ipo ni Zimbabwe.

Bi ọjọ ṣe n gori ọjọ ti alafia rẹ si n mẹhẹ, awọn eeyan bẹrẹ si ni sọrọ nipa ẹni ti yoo ropo rẹ

Ṣugbọn arekereke to n waye lori ọrọ yi ṣe afihan bi nnkan ko ṣe rọgbọ ninu ijọba rẹ́ pẹlu wi pe Mugabe fun ara rẹ ko fẹ gbe ijọba kalẹ.

Niṣe ni inu Mugabe ma n dun lati ma wo bi awọn ọmọ iṣẹ rẹ ti ṣẹ n jijadu ipo ti a si ma saba fi ori ara wọn gbarawọn.

Pẹlu bi awọn eeyan ṣe n ṣọ wi pe iyawo rẹ Grace ni yoo gun ori aleefa ti Mugabe ba papoda,Mugabe kede pe oun yoo dije fun ipo Aarẹ lọdun 2018 lẹni ọmọ ọdun mẹ́rìnléláàdọ́rùn ún.

Robert Mugabe lọdun 2008

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ni Zimbabwe, ẹni to lagbara bi ti Mugabe sọwọn

Koba fi le fidi rẹ́ mulẹ pe oun ko ṣetan lati gbe ijọba kalẹ, o kede ni osu keji ọdun 2016 wi pe oun yoo wa ni ijọba titi ti ''Olorun ba pe oun sọdọ.''

Amọ kii ṣe Ọlorun lo pe sọdọ bi kii ṣe awọn ọmọ ogun orileede Zimbabwe ti wọn fi si ahamọ lọjọ kẹẹdogun osu kọkanla 2017.

Ọjọ mẹrin lẹyin yi, wọn fi igbakeji rẹ Emmerson Mnangagwa ropo rẹ gẹgẹ bi Aarẹ amọ Mugabe kọ lati kọwe fipo silẹ.

Ni ọjọ kọkanlelogun osu kọkanla, bi ile asofin ṣe n jiroro lori boya ki wọn yọ nipo, olori ile asofin kede wi pe Robert Mugabe ti papa kọwe fipo silẹ.

Mugabe sẹto ki wọn ma ṣe pe oun ati awọn mọlẹbi rẹ lẹjọ lọjọ iwaju ati ki wọn ma ṣe fọwọ kan awọn ile iṣẹ rẹ.Won tun fun ni ile, ọmọ ọdọ,ọkọ ati ipo ẹni ayẹsi lagbaye.

Oni oye ni Mugabe ti kii si mu ọti.A ma fi oju sunukun wo ati ọrẹ ati ọta rẹ́ bakanna.

Ọpọ ni yoo ma ṣe iranti rẹ gẹgẹ bi ẹniti ọrọ da lẹnu rẹ to gba Zimbabwe lọwọ amunisin ṣugbọn ti oun gan wa dawọn pada si oko ẹru miran.

Igbe aye rẹ yoo ma wa pẹlu Zimbabwe fun igba pipẹ