Zimbabwe: Ìdìbò Akọ́kọ́ lẹ́yìn Mugabe yoo wáyé lọ́jọ́ Aje

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Zimbabwe yoo ṣe idibò si ipo aarẹ ọjọ Aje fun igba akọkọ lẹyin ti aarẹ ana, Robert Mugabe fipo silẹ ni oṣu kọkanla ọdun 2017.
Igbakeji Mugabe to di aarẹ lẹyin nigba to fipo silẹ Emmerson Mnangagwa ni oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu Zanu PF, bi alatako rẹ Nelson Chamisa ni oludijẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Movement for Democratic Change.
Chamisa ni awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti n bẹnu atẹ lu wipe ọjọ ori rẹ ti kere ju fun ipo aarẹ. Ẹni ogoji ọdun ni Chamisa ti Mnangagwa si jẹ ẹni ọdun marunlelaadorin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ Mnangagwa, Farai Mnangagwa Mlotshwa, sọ pe saa kan ni oun yoo lo nipo ti baba oun ba gbe'gba oroke ninu idibo na. Mnangagwa funra rẹ naa ni oun yoo yi kadara orilẹede naa pada si rere. Sugbọn Chamisa ni irọ nla ni gbogbo rẹ. O ni o jọ bi ẹni pe ajọ eleto idibo orilẹede yoo sẹ awuruju lati le ri pe Mnangagwa lo bori.








