Abdullahi Olatoyan: Iṣẹ́ fífọ gíláàsì ọkọ̀ ń tì mí lójú láti dẹnu ìfẹ́ kọ obìnrin

Àkọlé fídíò, Abdullahi Olatoyan: Iṣẹ́ fífọ gíláàsì ọkọ̀ ń tì mí lójú láti dẹnu ìfẹ́ kọ obìnrin

Yoruba ni ma tiju isẹ rẹ, idi isẹ ẹni si laa mọ ni lọlẹ.

Amọ fun Abdullahi Olatoyan, ẹni to n fi isẹ fifọ gilaasi ọkọ loju popo se isẹ jẹun, isẹ naa n tii loju pupọ, to si nira fun lati kọ̀nu ifẹ́ si obinrin.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọlatoyan, to maa n di tai bii oyinbo lasiko to ba n fọ gilaasi ọkọ loju popo salaye pe, iku baba oun lo sọ oun di ẹni to n fọ gilaasi ọkọ, ti oun si pa iwe ti oun n ka ni fasiti Ilọrin ti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe, o ti to ọdun meje si mẹjọ ti oun ti bẹrẹ isẹ naa, ti oun si n re owo jọ lati pada sile iwe.

Ọlatoyan ni oun maa n pa to ẹgbẹrun kan si meji naira lojumọ ti aje ba bu igba jẹ, to si tun fikun pe oun ti ta omi inu ọra ri ni Idumọta nipinlẹ Eko lati ran ara oun nileewe.

O wa gba awọn ọdọ bii tiẹ niyanju lati mase kawọ gbera maa reti owo lasiko ti nkan ba safẹrẹ diẹ, nitori o yẹ ki wọn maa wa nkan se lati ri owo fi mu afojusun wọn sẹ.