Cancer: àpọ̀jù ṣúgà nínú ẹ̀jẹ̀ ń ṣàkóbá fún àgọ́ ara èèyàn
Abajade iwadii naa ni kikun fihan pe ṣuga ko dara - Emma.
Ọpọlọpọ iwadii ni awọn onimọ ijinlẹ ti ṣe lori ohun to n ṣokunfa arun jéjéré.
Awọn onimọ sayẹnsi ni orilẹ-ede Faranse ṣẹṣẹ fi abajade esi iwadii wọn kan sita bayii.
Esi yii fihan pe ọti ẹlẹrindodo ni nkan ṣe pẹlu arun jẹjẹrẹ lara ẹda.
Emma Shields to ṣaaju iṣẹ iwadii naa ni France ni wọn ṣee pẹlu o le ni ẹgbẹrun ọgọrun un eniyan ni eyi ti wọn ṣe odiwọn ọti ẹlerindodo ti wọn n mu.
Emma ni laarin ọdun marun un ni wọn fi ṣe iwadii yii.
Esi rẹ fidiẹ mulẹ pe ṣuga apọju lara ni eyi to wa ninu ẹlẹrindodo n ṣokunfa arun jẹjẹrẹ lara eniyan.