Ọlọ́kadà Jigawa: Ìjọba Eko ti wá mọ́lé lọ́nà àìtọ́, a fẹ́ owó ‘gbà má bínú’

Awọn ọlọkada lati Jigawa

Oríṣun àwòrán, Twitter/The Lagos State Govt

Àkọlé àwòrán, Kini aduru gbogbo ero yii n bọ wa ṣe lEko lati ariwa ni ibeere awọn eniyan

Awọn eniyan mẹtalelọgọfa lati ipinlẹ Jigawa to wọ ipinlẹ Eko lẹkan soso pẹlu ọkada wọn, ti n beere fun biliọnu kan naira lọwọ ijọba ipinlẹ Eko pẹlu ẹsun pe wọn fi iya jẹ wọn.

Awọn eniyan mẹtalelọgọfa naa ni ile-isẹ eto aabo ayika ni ipinlẹ Eko fi panpẹ mu, ti wọn si fi ọrọ wa lẹnu wo, lẹyin ti awọn eniyan ta ile-isẹ aabo naa lolobo pe, awọn eniyan wọ ipinle Eko ni ọgọọrọ.

Agbẹjọro fun awọn ọlọkada naa, Abdullahi Yakubu sọ wi pe, ijọba ipinlẹ Eko gbọdọ san owo gba ma binu fun wọn, nitori wọn ti wọn mọle lọna aitọ, lai se pe wọn jẹ ọdaran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni wọn n beere fun ọkada wọn ati awọn ohun to jẹ ini wọn, ti ile-isẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko gba lọwọ wọn lasiko ifọrọwanilẹnuwo.

Awọn ọlọkada naa ni itimọle awọn tako ofin Naijiria to fun awọn ọmọ bibi orilẹede yii ni anfaani lati lọ lati ipinlẹ kan si omiran, lai si ẹru tabi ipalara.