Texas shooting: Ọlapàá ní Seth Ator tó pa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Texas ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù iṣẹ́ rẹ̀ ni

Oríṣun àwòrán, Instagram/sethator
Ileeṣẹ ọlọpaa niluu Odessa lapa iwọ oorun ipinlẹ Texas lorilẹ-ede Amẹrika ti fi orukọ agbebọn, Seth Aaron Atorto to yinbọn fawọn eeyan to to bi ogun lọjọ Satide sita.
Iṣẹlẹ iṣekupani ọhun eleyi ti eeyan marun un ti gbẹmi mi waye laarin ilu Odessa ati Midland nipinlẹ Texas.Wọ́n ti pa ẹni to yìnbọn pa ará Texas márùn ún -ọlọ́pàá
Alawọ funfun ni Ator jẹ, bẹẹ ni ọmọ odun mẹrindinlogoji si ni.
Iroyin to tẹ wa lọwọ lati orilẹ-ede Amẹrika sọ pe laipẹ yii ni iṣẹ bọ lọwọ Ọgbẹni Ator, eleyi to fihan pe o ṣeeṣe ki inu si maa bi lọwọ nitori o ṣẹṣẹ padanu iṣẹ rẹ.
Okunrin naa ni wọn ni o n wa mọto rẹ lọ lati agbegbe Midland si Odessa ni ipinlẹ Texas nigba to ṣadeede yinbọn pa agbofinro to kọkọ da ọkọ rẹ duro ko too tun kọju ibọn sawọn ero atawọn awakọ nibẹ.
Iroyin ni kete to yinbọn fawọn ero tan lo fi ọkọ ara rẹ silẹ to ji ọkọ awọn to n gbe lẹta tó si salọ.
Nigba to maa fi de Cinema Complex lo ko oni tiẹ nigba ti ọlọpaa miran gbebọn fun un.








