Leah Sharibu ṣì wà láàyè - Iléeṣẹ́ Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, @others
Ijọba Naijiria ni Leah Sharibu ko tii ku -Garba Shehu.
Leah Sharibu ni akẹkọbinrin ile iwe giram Dapchi ti awọn oniṣẹ ibi boko haram kọ̀ lati tu silẹ.Leah Sharibu pé ọmọ ọdún 16 ní àhámọ́ Boko Haram
Wọn ji akẹkọbinrin to le ni ọgọrun un gbe ni Government Girls Science and Technical school nipinlẹ Yobe loṣu keji ọdun 2018Dapchi School ṣí padà lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn án.
Lẹyin eyi ni wọn tu wọn silẹ ki boko haram to mu Leah silẹ pẹlu iroyin pe o kọ̀ lati gab ẹsin Islam ni tipatipa.Àyájọ́ ọmọbìnrin gba gbogbo ayélujára tán
Olubadamọran fun aarẹ Buhari lori eto iroyin ati ifitonileti gbogbo, Garba Shehu lo sọrọ itunu yii pe ijọbamọ pe Leah ṣi wa laaye.
O ni ijọba kọ̀ lati sọ ireti nu lori ọdọmọbinrin naa. Shehu sọrọ yii lọjọ abamẹta nilu Abuja.
Garba Shehu ni kaka ki ijọba Mohammadu Buhari sọ ireti nu, ijọba ṣẹṣẹ n gbe awọn igbesẹ tuntun ni lati ri Leah Sharibu gba pada lọwọ awọn oniṣẹ ibi boko haram.
Olubadamọran aarẹ ni iroyin ofege lo pọ ju ninu nkan ti awọn eniyan n sọ nipa Leah Sharibu.
O ni ijọba ṣi n sọrọ pẹlu awọn alakatakiti ẹsin Islam, ISWA lori fifi Leah Sharibu silẹ.
Garba ni awọn ajọ eleto aabo Naijiria fi n da wọn loju pe Leah ṣi wa laaye ati pe irọ ni pe o ti kú.
O ni ki awọn eeyan fun ijọba ni asiko diẹ sii nitori pe ijọba ko fẹ ṣi ẹsẹ gbé lori gbigba ọmọbinrin naa silẹ lakata awọn ISWA ni.
O ni gbogbo awọn ti awọn oniṣẹ ibi yii ji gbe nijọba ni lọkan lati gab pada sile.













