Taraba: Àwọn Ọlọpàá ní ìwádìí ṣì ń lọ lówọ lórí ikú Fadá

Taraba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilé isẹ́ olọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ní àwọn jàgùdà Pipo lo se iṣẹ ibi naa ti wọn si dana sun un ninu ọkọ re.

Olopaa Ipinlẹ Taraba ti ni awọn jaguda ti pa fada ti o n lọ lati pẹtu si ija laarin ẹya Tifi ati Jukun ni ipinlẹ Taraba.

Alukoro ile-isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, David Misal ṣalaye wi pe ,awọn jaguda lo se iṣẹ ibi naa ti wọn si dana sun Fada naa ninu ọkọ re.

Iroyin ti o tẹ wa lọwọ ni pe Fada David Tanko n lọ si ilu Takum fun ipade alaafia laarin Tiv ni Benue ati ẹya Jukun ni Taraba pelu awon olori ẹlẹsin miran.

Ija ẹlẹya mẹya ti o ti gbilẹ ni ipinlẹ naa lati igba pipẹ ni o fa ipade alaafia ti awọn olori ẹlẹsin ipinlẹ naa pe.

Ni bayii, ajọ ọlọpaa ipinlẹ naa ti pe fun iwadii to loorin lati fi panpẹ ọba mu ẹni ti ade ọrọ naa ba ṣi mọ lori.

Oga agba Ọlọpaa nilẹ yii, Muhammed Adamu ti paṣẹ pe ki ọlọpaa ipinlẹ naa wa ọdaran bẹẹ ri.

Bakan naa ni ko ṣai kẹdun pẹlu Ijọ Aguda lapapọ lori iku ojiṣẹ Olọrun naa ti awọn aṣebi dẹmi rẹ legbodo lai ro tẹlẹ.